Laipẹ yii ni iroyin deedee jade wi pe ọkan pataki lara awọn agba alẹnulọrọ, to tun jẹ ogbontarigi oloṣelu nipinlẹ Kwara, Amofin Kunle Sulyman ti jade laye.
A gbọ pe Amofin Sulyman dagbere faye lẹni ọdun mọkanlelọgọrin, lẹyin aisan rampẹ to nii ṣe pẹlu ọjọ ogbo.
Bi awọn eeyan ṣe n ṣedaro baba naa, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara naa fi atẹjade ibanikẹdun ranṣẹ si awọn mọlẹbi ati afẹnifẹre baba naa lati ki wọn ku ara fẹra ku.
Ninu ọrọ rẹ, Gomina AbdulRazaq ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi akikanju oloṣelu to maa n gbadun igboya awọn araalu.
O ni awọn yoo ṣafẹri rẹ gidigidi lẹka oṣelu, paapaa ninu idagbasoke eto oṣelu ipinlẹ Kwara.
No comments:
Post a Comment