Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lawọn mọlẹbi oloogbe ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Oluṣẹgun Ṣobiye ṣi n bẹbẹ fun idajọ ododo, lori bi wọn ṣe pa a.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni alaga ẹgbẹ awọn to n tun ọkọ ṣe, eyi ti wọn pe ni Nigeria Automobile Techinician Association, ẹka ti agbegbe Oke-Mọsan niluu Abẹokuta, Kẹhinde Amidu lu Ṣobiye pa.
Ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ to kọja yii la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye ni nnkan bi agogo mẹwaa owurọ, nigba ti wọn sọ pe Amidu, ẹni tọpọ mọ si Justo fi agidi fa Ṣobiye, ti wọn tun n pe ni Ọtun lulẹ lojiji, tiyẹn si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
Ko si nnkan meji ti wọn lo fa aawọ laaarin awọn mejeeji, bi ko ṣe ti ọmọdebinrin kan ti wọn sọ pe Justo paṣẹ fawọn ẹṣọ aabo inu abule ti wọn ti n tun ọkọ ṣe naa lati lu.
Ọmọ naa la gbọ pe wọn lu lalubami, ko to di pe ọrọ pada yiwó sibi ti wọn ko lero.
Oloogbe naa la gbọ pe o gbe ipo alaga silẹ fun Justo to ṣe pa, lori ikunsinu ti wọn lo ti wa nilẹ laaarin awọn mejeeji tẹlẹ.
Kii ṣe pe wọn ni Ọtun deedee gbe ipo naa silẹ, wọn lawọn kan ni wọn ji ọkọ ayọkẹlẹ kan gbe ninu ọgba lasiko ti oloogbe naa ṣi wa lori ipo gẹgẹ bi alaga.
Eyi ni wọn lo di wahala si oloogbe naa lọrun, to fi di pe wọn tii mọ ahaamọ ọlọpaa nigba to ku bi ọjọ mẹta ki asiko rẹ gẹgẹ bi alaga pari.
Ohun ti a gbọ ni pe Ọtun n gbiyanju lati fa ẹnikan kalẹ sipo alaga NATA ọhun, ti wọn si sọ pe ko dun mọ awọn kan ninu, pẹlu bi igbagbọ ṣe wa pe ẹni naa ni yoo wọle idibo.
Ọkọ ti wọn jigbe naa lo fa bi wọn ṣe ti oloogbe ati awọn kan mọ atimọle, to si jẹ pe nigba ti wọn yoo fi jade lahaamọ, wọn ti gbe Amidu to tun n jẹ Justo sipo alaga.
Latigba naa ni wọn sọ pe ikunsinu ti wa, ti onikaluku si n lọ lọtọọtọ, lai gun ara wọn, yatọ si pe ki wọn ki ara wọn, yala nibi ipade tabi nibikibi ti wọn ba ti pade ara wọn.
Lọjọ ti iṣẹlẹ aburu naa yoo waye, a gbọ pe ọmọọṣẹ tuntun ti iyawo Ọtun to n ta ounjẹ ninu ọgba ṣẹṣẹ gba lọjọ Aje, lo de lati wọnu ọgba, ti wọn si lawọn ọlọdẹ ko faaye gba lati wọle ni nnkan bi agogo meje aabọ owurọ.
Wọn ni bọmọ ọhun ṣe de ni wọn ti beere ibi to n lọ, to si sọ pe ọdọ iyawo Ọtun loun n lọ, ati pe oun ṣẹṣẹ debẹ ni lati maa ba wọn ṣiṣẹ ounjẹ.
Wọn ni awọn Justo sọ pe awọn ko mọ ẹni to n jẹ Ọtun, ati pe awọn ko le faaye gba a lati wọle. Awọn ọlọdẹ ọhun ni wọn pada lu ọmọ naa nigba to fẹẹ bẹrẹ sii ṣaigbọran.
Lẹyin o rẹyin ti wọn pada ṣilẹkun ọgba, ni ọmọ ọhun lọ sọ fun ọga rẹ nipa ohun to ṣẹlẹ, ti wọn si lobinrin ọhun ṣalaye fun ọkọ rẹ, nigba toun naa de ibi iṣẹ laaarọn ọjọ.
Pẹlu ibinu bi wọn fi lọmọ naa gbe ọmọ ọhun sinu ọkọ, to si gba ṣọọbu Justo lọ lati beere idi ti ọrọ fi ri bẹẹ.
A gbọ pe niṣe ni Justo da ọrọ ọhun si agidi, to si jẹ ki ọtun ṣeleri lati lọ fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti. Nibi ti wọn sọ pe Ọtun ti yi pada lati wọnu ọkọ rẹ, ni wọn sọ pe Justo ti fi ibinu fa a pada, to si jẹ iyalẹnu pe Ọtun ṣubu lulẹ, o si dagbere faye.
Gbogbo igbiyanju awọn to wa nibẹ ni wọn lo ja si pabo lati doola ẹmi Ọtun, idi ree ti wọn fi sare gbe e digbadigba lọ sile iwosan aladani kan, nibi ti wọn lawọn dokita ti wọn oku ni wọn gbe wa fawọn.
Lẹyin naa ni wọn tun pada gbe e lọ sile iwosan ijọba to wa ni Ijaye, ti wọn si lawọn dokita to wa nibẹ naa fidi rẹ mulẹ pe Ọtun ti jade laye.
Igba naa ni wọn too ṣẹṣẹ gbe oloogbe lọ si mọṣuari kan to wa ni Laderin, ko to di pe wọn pada sinu ọgba lati fi to iyawo atawọn ọmọ rẹ leti, ti ọrọ si di pẹntuka.
Eyi lo jẹ ki wọn ti ọgba abule naa pa, ti wọn si ni ki onikaluku gba ile rẹ lọ.
Lati ibẹ ni ọrọ ọhun ti de ẹkun ileeṣẹ ọlọpaa Kemta to wa lagbegbe Idi-Aba, ko to tun di pe wọn tare wọn si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwadii ọran, iyẹn SCID lati tẹsiwaju ẹjọ naa.
Wọn lohun ti Justo n sọ f’awọn ọlọpaa ni pe oun ko fa oloogbe naa, bi ko ṣe pe asiko toun dii mu lasan, lo ṣubu lulẹ, to si ku loju ẹsẹ.
Awọn ọlọpaa naa ni wọn lo pada fi afurasi ọhun, Amidu silẹ lahaamọ, ti wọn sọ fawọn mọlẹbi lati lọ ṣayẹwo ‘Autopsy’ lati mọ iru iku to pa Ọtun.
Gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Oluṣeyi Babaṣeyi sọrọ lori foonu ati atẹjiṣẹ, ko le fidi rẹ mulẹ lo ja si pabo, pẹlu bi ọkunrin naa ṣe kọ lati ba wa sọrọ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ jẹ ko di mimọ pe awọn ọlọdẹ to lu ọmọdebinrin naa yoo foju ba ile-ẹjọ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026.



No comments:
Post a Comment