Ọnarebu Oluṣọla Arikẹ Ayekootọ jawe olubori gẹgẹ bi oludije ADC fun ipo aṣoju-ṣofin agbegbe Alimọṣọ l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 25, 2026

Ọnarebu Oluṣọla Arikẹ Ayekootọ jawe olubori gẹgẹ bi oludije ADC fun ipo aṣoju-ṣofin agbegbe Alimọṣọ l'Ekoo

idunnu ti ṣubu layọ fun gbajumọ sọrọsọrọ, to tun jẹ agba oniroyin nni, Ọnarebu Oluṣọla Arikẹ, tọpọ awọn eeyan mọ si Ayekootọ, lori bo ṣe jawe olubori gẹgẹ bii oludije fẹgbẹ oṣelu ADC, tipinlẹ Eko, fun ipo aṣoju-ṣofin, agbegbe Alimọṣọ, ninu ibo to n bọ lọdun 2027.

Nibi ibo pamari ẹgbẹ naa to waye lọsẹ to kọja yii ni akọni obinrin oloṣelu yii ti fẹyin ẹni ti wọn jọ jade dupo ọhun iyẹn Ọnarebu Mogeed Anjọlaiya janlẹ patapata.

Bo tlẹ jẹ pe ọpọ igbese lo ti waye ninu ẹgbẹ ADC lori ẹni ti yoo ṣoju wọn fun ipo aṣoju ṣofin ọhun, ko to di pe awọn mejeeji pade lori papa ti Arikẹ si fẹyin ọkunrin naa janlẹ.

Gẹgẹ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC agbegbe Alimọṣọ, ṣe wi lọjọ ti wọn dibo ọhun, wọn awọn mọ ọn mọ ṣatilẹyin fun Arikẹ Oluṣọla gẹgẹ bi oludije nitori awọn mọ pe o ka ipa ẹ.

Wọn ṣapejuwe ẹ bi ẹni to ni iriri lati le ṣe aṣoju wọn to ba delu Abuja, ti yoo si fi ran awọn Alimọṣọ lọwọ.
 
Ni bayii, oludije to ṣẹṣẹ gba tikẹẹti naa, Ọnarebu Arike Oluṣọla ti wa fi ẹmi imoore ẹ han sawọn eeyan agbegbe Alimọṣọ lori akitiyan lati jawe olubori.

Bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ awọn oloye atawọn agbaagba ẹgbẹ ADC fun oore ọfẹ ti wọn ni si oun lati gba tikẹẹti ọhun.

O wa mu da wọn loju pe oun ko ni jawọn nitanmọ, ati pe wọn ko ni kabamọ igbagbọ ti wọn ni si oun.

Arikẹ tun lo akoko naa lati rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC lati jọ ṣiṣẹ pọ nitori agbajọwọ la fi n sọya, ki wọn jẹ kawọn jọ ṣiṣẹ pọ lati ri pe ẹgbẹ wọn jawe olubori lati ipo aarẹ, aṣofin agba, aṣoju-ṣofin, gomina ati ọmọ ile igbimọ aṣofin.

O sọ pe, o da oun loju ẹgbẹ wọn ni yoo jawe olubori ninu ibo ọdun 2027. O ni ki APC maa palẹ ẹru wọn mo, ADC ti de lati gbajọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI