Ẹgbẹ Ọdọ nilẹ Naijiria, iyẹn "Youth Party", ẹka tipinlẹ Ogun ti sọ pe ẹnikan ṣoṣo ti awọn ni igbagbọ rẹ lati ṣoju awọn nile igbimọ aṣofin agba, ninu eto idibo ọdun 2027 ni Amofin Goke Kuye.
Awọn alakoso naa sọ pe ekun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nilo ẹni to kaju oṣuwọn lati ṣoju wọn nilẹ igbimo aṣofin agba to wa niluu Abuja, idi ree ti wọn fi kede Kuye gẹgẹ bi ọmọ oye lati gbe asia ẹgbẹ.
Nibi eto idibo abẹle ẹgbẹ naa to waye ni olu-ileeṣẹ ẹgbẹ naa to wa niluu Abẹokuta, ni wọn ti panupọ pe ki awọn fa Kuye kalẹ fun ipo naa
Gbogbo awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ẹgbẹ oṣelu naa lati ẹkun Ifo, Ewekoro, Obafemi Owode, Guusu Abeokuta South, Odeda ati Ariwa Abeokuta ni wọn kopa ninu eto ọhun ti wọn ti fẹnu ko lati fa Kuye kalẹ.
Nigba to n sọrọ ni kete ti wọn kede rẹ, o fi ẹmi imoore han si awọn alakoso ẹgbẹ oṣelu ọhun, fun igbagbọ to sọ pe wọn ni ninu oun lati ṣiṣẹ isin ilu.
O wa ṣeleri pe oun yoo ṣoju wọn daadaa, toun yoo si jẹ ki wọn ni imọlara ipo aṣofin, bi wọn ba fi ibo gbe oun wọle.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe, “Iwuri nla lo jẹ fun mi pe ẹ ẹyin oloye ati ọmọ ẹgbẹ wa yii, ni igboya ninu mi, nipa yiyan mi lati lọ ṣoju yin. Eleyii kii ṣe aṣeyọri fun emi nikan, bi ko ṣe fun iṣẹ ọpọlọ ti awọn adari to ṣee fọkan tan, ailẹbọ lẹru, ati iṣejọba alafojusun.
“Mo tẹwọ gba ojuṣe yii pẹlu irẹlẹ ati ọkan ifarajin lati ṣiṣẹ sin awọn ara aarin gbungbun ipinlẹ Ogun pẹlu iwa ọmọluwabi, ifarajin ati aifohunkohun pamọ.”
O wa ṣeleri pe oun yoo mu ọrọ eto ironilagbara awọn ọdọ, idagbasoke eto ọrọ aje, eto ẹkọ, eto ilera ati igbayegbadun araalu kaakiri ẹkun naa lọkunkundun.
Nigba toun naa n ba awọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ, alaga ẹgbẹ oṣelu Ọdọ (Youth Party) naa, Arabinrin Olamide Okunowo gbe oṣuba kare fawọn oloye ati ọmọ ẹgbẹ, to si jẹ ko di mimọ pe pẹlu alaafia ni eto idibo wọn fi waye.
Okunowo sọ pe bi Kuye ṣe jawe olubori ṣafihan ifarajin awọn ọmọ ẹgbẹ si awọn alakoso ati itẹsiwaju.
O wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe wọn di ẹgbẹ ti ilu n tẹwọgba lati ṣe aṣeyọri ninu eto idibo ọdun 2027.
Alaaja Akinwande lo ṣoju ajọ eleto idibo INEC nibi eto idibo abẹle naa, ti awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ko si gbẹyin nibẹ.
No comments:
Post a Comment