Aarẹ Adetola EmmanuelKing gbe oṣuba kare fun Gomina Abiodun lori idagbasoke eto ẹkọ l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 26, 2026

Aarẹ Adetola EmmanuelKing gbe oṣuba kare fun Gomina Abiodun lori idagbasoke eto ẹkọ l'Ogun


Alaṣẹ ati oludasile ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited nilẹ Naijiria, Aare Adetola EmmanuelKing ti gbe oṣuba kare fun Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun lori akitiyan ati ipa to n ko lẹka eto ẹkọ.

Aarẹ EmmanuelKing lo gbe oṣuba naa nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade awọn akẹkọọ saa ọdun 2026 nile ẹkọ girama ti RSS, iyẹn Remo Secondary School (RSS) to wa niluu Sagamu, ipinlẹ Ogun.

Ara ọtọ ni ayẹyẹ ikẹkọọjade naa gba waye, ti wọn si ṣe e ni ilana ti fasiti.

Nigba to n sọrọ, Aarẹ EmmanuelKing to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọjade nile ẹkọ naa, iyẹn Remo Secondary School Old Students' Association (RSSOSA), gbe oriyin fun awọn eeyan naa pẹlu aṣeyọri yii, to si rọ wọn lati tubọ gbajumọ ọjọ iwaju wọn.

Aarẹ EmmanuelKing gbe oṣuba kare fun awọn olukọ ati obi awọn akẹkọọ naa, to fi mọ awọn alakoso ile-ẹkọ ọhun fun akitiyan wọn ati itọnisọna ti wọn fun awọn akẹkọọjade.

O sọ pe bi ile-ẹkọ naa ṣe n dagba siwaju, ko ṣẹyin Gomina Dapọ Abiọdun pẹlu akitiyan rẹ lẹka eto ẹkọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI