Ọga ọlọpaa tuntun nilẹ Naijiria, Tunji Disu ṣabẹwo si Gomina AbdulRazaq ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 12, 2026

Ọga ọlọpaa tuntun nilẹ Naijiria, Tunji Disu ṣabẹwo si Gomina AbdulRazaq ni Kwara


Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria, Ọlatunji Disu ti ṣe abẹwo si Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara, nibi to ti ṣeleri ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu ijọba ipinlẹ naa.

Ọjọ Aje, ọsẹ yii la gbọ pe Disu ṣe abẹwo naa pẹlu ikọ akọwọrin rẹ si ile ijọba to wa niluu Ilorin.

Nibẹ ni ọga ọlọpaa naa ti ṣeleri pe eto aabo to pe ye yoo wa fun gbogbo ara ati olugbe ipinlẹ Kwara patapata, ti wọn yoo si ni ifọkanbalẹ ọtun.

Disu sọ pe pataki ojuṣe awọn ninu iwe ofin ilẹ Naijiria ni eto aabo araalu patapata, to si ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo ni ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu awọn alakoso nipinlẹ naa.

O ni gbogbo awọn alẹnulọrọ patapata lawọn yoo ri pe wọn ba ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu wọn, lati le jẹ ki eto aabo tubọ kẹsẹjari.

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lẹyin abẹwo naa, Disu jẹ ko di mimọ pe lara igbesẹ lati jẹ ki eto aabo fẹsẹ rinlẹ daadaa ni abẹwo iṣẹ naa jẹ.

O loun mọ ipenija to n koju eto aabo nipinlẹ Kwara, to si ni igbesẹ ọna abayọ ti bẹrẹ bayii.

O wa fi da gbogbo araalu nipinlẹ naa loju pe awọn yoo ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe wọn n sun oorun asundọkan bayii, ti yoo si fi ọkan wọn balẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI