"A ko nii gbagbe wọn, ati awọn miran bii ti wọn.." - Gomina AbdulRazaq kẹdun iku awọn ọmọ ogun to ku sọwọ awọn agbebọn ni Kaiama - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 20, 2026

"A ko nii gbagbe wọn, ati awọn miran bii ti wọn.." - Gomina AbdulRazaq kẹdun iku awọn ọmọ ogun to ku sọwọ awọn agbebọn ni Kaiama


"Ni nnkan bi agogo mẹta oru oni, a padanu awọn ọmọ ogun mẹta lasiko ti wọn doju kọ awọn agbebọn aṣekupani ti wọn wọ Kemanji, Kaiama," Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi soju opo ayelujara rẹ lalẹ ọjọ Aje.

Gomina AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe ẹdun ọkan nla ni iku awọn ọmọ ogun naa jẹ foun, nitori pe asiko ti wọn n doola ẹmi ati dukia araalu ni wọn pade iku ojiji.

"Kii ṣe pe awọn akikanju ologun yii koju ikọlu awọn agbebọn naa, bi wọn ṣe pe wọn ko tun gba wọn laaye lati wọ agbegbe naa, ti wọn si rii pe wọn ko jẹ ki wọn ji ẹnikẹni gbe, gẹgẹ bi erongba awọn agbebọn naa.

"Mo fi tọkantọkan ranṣẹ ibanikẹdun si mọlẹbi awọn afẹnifẹre awọn akikanju ti wọn fi ẹmi wọn lelẹ fun ilẹ baba wọn.

"A ko nii gbagbe wọn, ati awọn miran bii ti wọn ni oniruuru ẹka lorileede yii."

Gomina wa ṣeleri lati dide iranlọwọ fun awọn mọlẹbi ati ololufẹ wọn, pẹlu idaniloju pe wọn ko nii da ohunkohun si lati fi daabo bo ẹmi ati dukia araalu.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI