Gomina AbdulRazaq ṣabẹwo s'awọn ọmọ ogun to farapa loju ogun ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 21, 2026

Gomina AbdulRazaq ṣabẹwo s'awọn ọmọ ogun to farapa loju ogun ni Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti ṣabẹwo ibanikẹdun s'awọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria ti wọn farapa loju ogun nijiọba ibilẹ Kaiama.

Laipẹ yii ni awọn agbebọn aṣekupani ṣe ikọlu s'awọn eeyan nijọba ibilẹ naa, pẹlu erongba lati ji awọn eeyan gbe.

Gbogbo akitiyan awọn agbebọn naa la gbọ pe awọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria sọ di asan ati otubantẹ.

Niṣe lọrọ naa dabi ogun abẹle, nigba ti awọn agbebọn naa ati awọn ọmọ ogun kọju ija sira wọn, ti ibọn si n ro lakọ-lakọ, eyi to ko ibẹrubojo sọkan awọn eeyan, ti awọn ọmọ ogun si farapa, ti awọn miran si jade laye.

Gomina AbdulRazaq nibi abẹwo to ṣe lọ si ile iwosan lọjọ Iṣẹgun, oni, ṣeleri iranlọwọ fun awọn ọmọ ogun ọhun.

Nibi abẹwo ọhun ni gomina ti kede iranlọwọ ogun miliọnu naira fun ọmọ ogun kọọkan to fi ẹmi rẹ lelẹ, ati miliọnu marun-un naira fun ọmọ ogun kọọkan to farapa.

Gomina sọ pe awọn eeyan naa lo ọkan akikanju lati fi ẹmi ara wọn lelẹ, ti awọn si gbọdọ fi imọriri han si wọn, to si mọ awọn to farapa.

Akọwe agba igbimọ iṣakoso ile iwosan nipinlẹ Kwara, Dokita Malik Adulraheem; alakoso agba ile iwosan KWASUTH, Dokita Ahmed AbdulKadir, ati awọn olori eleto aabo lo gba gomina ati ikọ akọwọrin rẹ lalejo si ile iwosan ọhun.

“A wa nibi lati ri awọn ọmọ ogun ti wọn farapa nibi ikọlu to waye laipẹ yii. Ikọlu a-mọ-ọn-mọ-ṣe ni ikọlu ọhun, to si ba ni lọkan jẹ,” gomina sọ bẹẹ f'awọn akọroyin.

“Awọn ologun ati awọn eleto aabo yooku ti n fọwọsowọpọ loootọ, bẹẹ si ni ijọba yoo maa ṣe iranlọwọ to ba yẹ fun awọn eleto aabo wa, bi wọn ṣe n ṣiṣẹ wọn. A mọ riri ipa ti wọn n ko, awa naa yoo si tubọ maa ṣe ojuṣe wa.

AbdulRazaq ti wa fidi rẹ mulẹ pe awọn ologun ati awọn eleto aabo ti dena oniruuuru ikọlu to yẹ ko waye nipa iṣẹ olobo to n tẹ wọn lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI