Peter Okoye yi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ pada nitori ija oun pẹlu ekeji rẹ, Paul - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 20, 2026

Peter Okoye yi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ pada nitori ija oun pẹlu ekeji rẹ, Paul


Ọkan lara ibeji P-Square, awọn olorin takasufe nni, Peter Okoye ti kede sita pe oun ko nii maa ṣayẹyẹ ọjọ ibi oun ni gbogbo ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdọọdun mọ bayii.

Igbesẹ yii lo waye pẹlu erongba rẹ lati jinna si ekeji rẹ, Paul Okoye ti wọn jọ jẹ ibeji lati kekere.

Peter ti wọn tun n pe ni Mr P bayii ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo ọgbọn ọjọ ọdọọdun loun yoo maa ṣayẹyẹ ọjọ ibi oun.

O ni ki ẹnikẹni ma ṣe ki oun ku ayẹyẹ ọjọ ibi mọ ni ọjọ ti wọn ti mọ tẹlẹ, bẹẹ si loun ko nii gba ẹbun ọjọ lọwọ ẹnikẹni lọjọ naa.

Peter sọ pe bi ẹnikẹni yoo ba foun ni ẹbun tabi ki oun fun ayẹyẹ ọjọ ibi, ghogbo ọgbọn ọjọ ọdọọdun ni ki wọn maa ṣe e bayii.

Fun awọn to ba mọ ibeji P-Square naa daadaa, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanlaz ọdun 1981 ni wọn bi wọn gẹgẹ bi ibeji, ti wọn si n ṣayẹyẹ ọjọ ibi latigba naa.

Ṣadede ni aawọ bẹ silẹ laaarin awọn mejeeji lẹyin ti wọn ti jọ kọrin fun ọpọlọpọ ọdun nilẹ Naijiria ati kaakiri agbaye.

Lati ọdun 2024 ni awọn ilu mọ-ọn-ka olorin takasufe naa ti pin gaari, ti wọn ti lọ lọtọọtọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI