Lọjọ Ẹti tii ṣe Furaide to kọja yii ni ẹgbẹ awọn oniṣẹṣẹ nilẹ Ẹgba to wa niluu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun dide lati bẹ awọn alalẹ lọwẹ fun itusilẹ awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn jigbe nipinlẹ Ọyọ.
Awọn oniṣẹṣẹ naa ni iyawo gbajugbaja ọba alaye nipinlẹ naa, Olori Ọmọlara Fashola-Macgregor lewaju wọn lati parọwa si awọn alalẹ to tẹ ilu Ẹgba do.
Kaakiri ojubọ awọn to tẹ ilẹ Ẹgba do ni awọn eeyan naa ti lọ rawọ ẹbẹ pe ki wọn dide lati ja fun itusilẹ awọn to wa nigbekun naa.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ni nnkan bi ọjọ diẹ sẹyin ni awọn ajinigbe aṣekupani ti awọn akẹkọọ mọkandinlogoji ati olukọ mẹfa gbe, ti wọn si ge ori ọkan lara awọn olukọ naa lati fi pa aroko si ijọba.
Nigba to n sọrọ, Olori Ọmọwe Fashola-Macgregor to lewaju eto adura naa sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ fun awọn gẹgẹ bi abiyamọ, lati rii pe awọn ọmọ kekeekee wa ninu igbekun fun ọjọ pipẹ.
Olori sọ pe awọn nigbagbọ pe awọn alalẹ ilẹ Ẹgba yoo dide lati ja fun itusilẹ awọn to wa ninu igbekun naa.
Lara awọn agbegbe ti wọn lọ lati ṣeto adura naa ni oke Olumọ, orori Ṣodẹkẹ, ojubọ Itoku ati awọn ojubọ miran kaakiri ilu Ẹgba to ṣe pataki.
Nibi awọn ojubọ ọhun, ni wọn ti bẹbẹ pe ki awọn alalẹ dide lati lọ tu awọn to wa ninu igbekun naa silẹ ko too to ọjọ meje.
Wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ko ṣe ifẹhonu han, bi ko ṣe pe awọn dide lati rawọ ẹbẹ si awọn alalẹ lati dide fun itusilẹ awọn eeyan naa ni kiakia.
Nigba to n sọrọ, Olori Fashola-Macgregor sọ pe lati ọdun pipẹ ni awọn alalẹ ti n dide iranwọ fun awọn to ba ke pe wọn.
O ni kii ṣe pe awọn n daabo bo aṣa ati iṣẹṣe nikan, bi ko ṣe pe awọn tun n wa ọna abayọ nilana ibilẹ fun iranwọ atokewa.
“A wa nibi lati rọ awọn baba nla wa ati ẹmi awọn akọni wa lati dide ja fun awọn rogbodiyan to n ṣẹlẹ lorileede,” Olori sọ bẹẹ.
“Adura wa duro lori bi awọn ti wọn jigbe yoo ṣe gba itusilẹ, ti wọn yoo si pada sile wọn. A ni igbabọ pe bi awọn eeyan ba fi imọ ṣọkan nipa ifẹ, awọn alalẹ yoo dide iranwọ.”
No comments:
Post a Comment