Awọn alakoso ileeṣẹ Lafarge to n ṣe simẹnti kaakiri agbaye ti sọ pe awọn ti yi orukọ awọn pada bayii, ati pe HBM Nigeria Plc ni awọn n jẹ bayii.
Ọpọ awọn to gbọ nipa ayipada tuntun yii lo n ṣe ni kayeefi, nitori pe airotẹlẹ ni, ati pe fun ọpọlọpọ ọdun ni wọn ti fi jẹ orukọ naa.
Ninu atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ naa fi sita lọjọ Aiku,wọn jẹ ko di mimọ pe ayipada naa pọn dandan pẹlu bi awọn onipin idokoowo tuntun ṣe gba akoso nipa agbekalẹ ati ilana tuntun.
Nigba to n sọrọ, alakoso agba ileeṣẹ naa, Lolu Alade-Akinyẹmi jẹ ko di mimọ pe igba ọtun lo bẹrẹ bayii, nipasẹ afojusun ati agbekalẹ ọtun, eyi ti yoo tubọ jẹ ki wọn gbilẹ sii nipa okoowo ṣiṣe.
Bakan naa, alaga igbimọ iṣakoso ileeṣẹ HBM Nigeria Plc, Gbenga Oyebọde fidi rẹ mulẹ pe ayipada ọtun yii ni awọn ṣagbekalẹ rẹ lojuna lati tubọ duro lori awọn aṣeyọri ati ilana ti wọn fi n lọ siwaju loorekoore.
No comments:
Post a Comment