Niṣe lọrọ di boolọ o yago lọna nigba ti aṣita ibọn ba gbajugbaja oloye kan nipinlẹ Ondo, to si ṣe bẹẹ ku loju ẹsẹ.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Ayeka, nijọba ibilẹ Okitipupa , ipinlẹ Ondo ni ijamba naa ti waye lopin ọsẹ to kọja yii.
Ori la gbọ pe ibọn ọhun ti ba agba Oloye naa ti a ko tii mọ orukọ rẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
Oloye ọhun ni wọn lo wa lara awọn to n ṣagbatẹru eto isinku to n lọ lọwọ.
Lojiji la gbọ pe ibọn kan lara awọn oṣiṣẹ aabo to wa nibi eto isinku naa gbe dani ti yin, to si lọ ba agba Oloye naa lori.
Ki oloju too ṣẹ ẹ, Oloye naa ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra, o si ti ku.
Gẹgẹ bi awọn to wa nibi iṣẹlẹ naa ṣe ṣalaye, wọn ni eto isinku ọkan lara awọn oloye ilu naa ni wọn n ṣe lọwọ, ki agbako miran too tun ṣẹlẹ.
Kayeefi nla ni iṣẹlẹ ọhun ṣi n jẹ fun gbogbo awọn ara agbegbe yii, paapaa awọn to wa nibẹ lasiko iṣẹlẹ naa.
Bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ, ṣugbọn ohun ti awọn eeyan sọ nibẹ ni pe, o ṣeeṣe ko jẹ pe ibọn yinyin wa lara eto ati ilana isinku Oloye ọhun.
Ju gbogbo rẹ lọ, a ko tii mọ orukọ Oloye ti n sinku rẹ lọwọ, ati Oloye to pada iku ojiji lai ro tẹlẹ yii.
Nigba to n fidi rẹ mulẹ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abayọmi Jimoh sọ pe ọwọ ti tẹ afurasi kan, to si ni afurasi naa ti wa lahaamọ awọn.
Jimoh fi kun ọrọ rẹ pe iwadii kikun ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.
No comments:
Post a Comment