Ile-igbimọ aṣofin orileede Naijiria ti sọ pe ko erongba lati ṣe agbeyẹwo lori iwe ofin eto idibo ti wọn gbe kalẹ lọdun 2026.
Ile igbimọ naa sọ pe eto idibo ọdun 2027 ti sunmọ etile, fun idi eyi, ko id ikan ni pato fun wọn lati ṣe agbeyẹwo iwe ofin eto idibo naa.
Ọrọ yii lo jẹyọ lori idajọ ile-ẹjọ agba ilẹ Naijiria nipa jijẹ ọmọ ẹgbẹ, fifa oludije kalẹ ati awọn miran.
Alaga ile igbimọ aṣofin lori eto iroyin ati ọrọ araalu, Sẹnetọ Yemi Adaramodu lo fidi ọrọ naa mulẹ, to si ni ile igimọ ti pari iṣẹ lori ofin eto idibo, ati pe wọn ko nii gbe igbesẹ kankan lasiko ti gbogbo ẹgbẹ oṣelu n ṣe ipalẹmọ fun eto idibo.
Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwerọ to ṣe laipẹ yii, Adaramodu sọ pe ko sẹni ti yoo tẹọ gba agbeyẹwo kankan lasiko yii, ṣaaju eto idibo ọdun 2027.

No comments:
Post a Comment