Buhari ko le so eso rere forileede Naijiria o - Fayose pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 19, 2017

Buhari ko le so eso rere forileede Naijiria o - Fayose pariwo sita

Kii se akoko ree ti Gomina ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose maa bu enu ate lu isejoba Buhari pelu bi nkan se le koko fawon araalu to si je pe se lopo awon araalu n tiraka lati rowo mu lo senu.

Gomina naa so pe awon omo orileede Naijiria ko nilo idanilekoo kankan mo lati ma se gba egbe oselu APC laye mo ninu idibo apapo to n bo lodun 2019 eyi to seese ki Aare Buhari so pe oun fee se eleekeji.

Gege bo se so, o ni ko seni to le won alaafo to wa laarin ijoba ti Aare ana, Omowe Goodluck Jonathan se ati eyi ti Aare Buhari n se lowo yii nipa idagbasoke. O ni igimu jina soro.

Gomina Fayose soro yi lakoko to n bawon oniroyin soro nipinle naa. Ninu atejade ti oga agba leka iroyin fun gomina, Ogbeni Adelusi Idowu fi sita, o so pe ibanuje nla lo je pe ijoba odun meji egbe oselu APC labe Buhari ti mu ki igbe aye le koko mo awon araalu kaka ki n de fun won.

"Naijiria ti a lala ri yato si nkan ti a ri bayii. Awon nkan ti mo so nipa Aare Buhari ti n wa si imuse. Ki akoko idibo too de, mo so pe kawon eeyan ma dibo fun un. Ebi n pawon omo Naijiria, won si ti n kabamo. Bi eni ti ko jamo nkan ba dije pelu Buhari lodun 2019, Buhari yoo fidi Remo. Awon omo Naijiria ko nilo idanilekoo mo lati mo pe ko ye ki won dibo fun Buhari mo lodun 2019. O ti doju han gbangba.

"Opo awon to dibo fun un to fi wole ni won ko mo eeyan to je nitori pe won sese n pe omo ogoji odun ni, awon to je pe omo owo ni won si je nigba to se ijoba Olorun lodun 80s. Aladase nijoba e atipe yato si pe o ti isejoba ri lakoko ologun, ko ni awon amuye lati dari orileede yii. Tunde Idiagbon lo baa sejoba lodun naa lohun.


"Ko kaju osuwon rara. E o le fi we Aare ana, Goodluck Jonathan. Jonathan gba ijakule nibi idibo to sagbateru e." Fayose

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI