IDIBO GOMINA LODUN 2019: IJEBU ATI YEWA SETAN LATI MU OMI NINU KOTO KAN NAA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 19, 2017

IDIBO GOMINA LODUN 2019: IJEBU ATI YEWA SETAN LATI MU OMI NINU KOTO KAN NAA

 
Bi idibo gomina nipinle Ogun ti se n sunmo etile bayii, oro naa ti fi n han gbangba gbangba pe awon Ijebu ti n dana sile bayii lati gbee koju awon Yewa nibi idibo gomina odun 2019 to n bo lona, pelu bo se je pe orin tawon Yewa n ko bayii nip e “Yewa lo kan; Awa lo kan. Idibo gomina odun 2019, Yewa lo kan.”

Bee ni won lawon Ijebu naa ti n lu ilu “Apepe” bayii pe, “Ao ni gba, awa la ni; Aga gomina ipinle Ogun, Awa la ni”. Ti won si n rawo ebe sawon omo ipinle Ogun pe ki won fowosowopo pelu awon lodun 2019.

Titi di akoko yi, ko sorin meji tawon omo bibi Yewa n ko bayii, bi ko se orin “YAYI la fe” lo, iyen Senato Adeola Olamilekan Solomon to n soju ekun kan nipinle Ekoo nile igbimo asofin agba nilu Abuja. Bee lawon kan n bebe korin pe ki won fun eni to ti pe nibi ere ije naa laye, iyen Gboyega Nasiru Isiaka, GNI, eni to ti tiraka lati du ipo naa leemeji.
Bee lawon Ijebu naa o leni meji ti won fee fun laye bi ko se Onarebu Ladi Adebutu Keshinton, topo mo si LADO, eni to je okan lara awon omo ogbontarigi onisowo nni, Adebutu Keshinton, topo mo on si Baba Ijebu.

Sibe, a o gbodo foju fo okan lara awon awon agba oselu nni, toun naa tiraka se ipo keta nibi idibo gomina nipinle naa, Otunba Olatunde Olarotimi Paseda, eni toun naa ti n so pe, oun ko nii gba lodun 2019 naa.

Ohun to tun n je kayeefi ni bayii ni bi Gomina Ibikunle Amosun se ti n so pe, ko seni ti yoo gba aga naa nidi oun ninu awon to n leri yi naa. Amosun so pe oun nikan loun mo eni ti yoo gba aga naa lodun 2019.

Sugbon ohun to tun n je iyalenu ni tawon agba oselu meta nni, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Oloye Olusegun Osoba ati Otunba Gbenga Daniel ko se fi ara won sere lasiko yii, to je pe tosan toru ni won fi n se ipade bonkele lati je ki ipinu won wa si imuse.


Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo, won ni ipade tawon agba oselu naa n se ni bi won ko se ni fun Gomina Amosun laaye lati fa eeyan kale gege bi gomina ipinle Ogun lodun 2019, iyen eni to n so pe yoo gba ipo naa lowo oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI