Eyi ni bi Desmond Nwachukwu se di Aare egbe sorosoro FIBAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 24, 2017

Eyi ni bi Desmond Nwachukwu se di Aare egbe sorosoro FIBAN

Desmond
Bo tile je pe bi ala lo si n je fokunrin naa ti won sese dibo yan gege bi Aare egbe sorosoro to daduro lorileede Naijiria, iyen Freelance Broadcasters’ Association of Nigeria, FIBAN lori bo se yege nibi eto idibo to koja.

Desmond Abiodun Nwachukwu lokunrin naa, eni to je alaga ana fegbe naa nipinle Ogun. Gege bii iwadii ti AWIKONKO se, a gbo pe, ko too di pe won seto idibo naa lojobo Tosde ose to koja lo ti nn kaakiri odo awon agbaagba ninu egbe naa, to si n salaye idi to fi fee dupo aare egbe naa.

Latigba naa ni a gbo pe won ti n fun ni amoran lori igbese to le gbe lati rii pe o depo naa pelu iranlowo awon oludibo. Sugbon nigba ti ipolongo idibo naa bere ni pereu lose bii meji seyin lara e ko ti bale mo.

Ohun taa gbo nipe, okunrin naa, iyen Desmond ko lee sun oorun wakati meta lale, ironu bi aare egbe naa yoo se tee lowolo n ro. Awon kan to sunmo daadaa je ko ye wa pe, okunrin naa di afadura-jagun ojiji lori ko le depo naa.

Won ni bi Desmond se n gbadura kira-kira, bee lawon pasito atawon aafa lorisiri naa ko dawo adura duro lori aseyori Desmond gege bi Aare egbe naa, titi di ojo idibo ku ola ni won fi n gbadura. Bakanna la tun gbo pe inu aawe biribiri lokunrin naa wa.

Lojobo Tosde ose to koja ti idibo naa waye nilu Ibadan, nibi tawon agbaagba egbe naa ti pe jo pelu awon oludibo ati ajo eleto-idibo egbe naa, tawon eeyan lorisiri naa si wa nikale lati mo eni ti yoo jawe olubori laarin awon meji to n dupo naa.

Nigba tidibo naa bere, gege bi ohun ti a gbo lati enu awon to n sakiyesi okunrin naa, won ni se lo n gbadura kikan-kina sinu pe ki Olorun gbakoso, nitori pe awon ipinu rere toun ni fun idagbasoke ati ilosiwaju egbe naa, asiko yi loun fe koo wa si imuse.

Sugbon nigba ti ajo eleto idibo naa bere sii ka ibo naa, oruko Desmond lo poju ninu oruko ti won n da, nibe lawon kan ti bere sii bo lowo pe o ku oriire. Leyin-o-reyin ni won rii pe ibo mokanlelaadorin (71votes) ni Desmond ni, ti enikeji ti won jo n dije si ni ibo metadinlogbon(27).

Loju ese ni won so pe Yemi Sonde, Jigan Akala to je Aare egbe naa ti so pe, kawon omo egbe naa bere sii dari gbogbo oro to ba niise pelu egbe naa si Desmond, ki wahala le kuro lorun oun.


Gbara ti won kede Desmond gege bi eni to jawe olubori lawon ololufee ti gbee soke, lati baa sajoyo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI