Aarẹ Adetola ba Ọnarebu Elegbeji yọ lori aṣeyọri idibo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 20, 2025

Aarẹ Adetola ba Ọnarebu Elegbeji yọ lori aṣeyọri idibo

Alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited kaakiri agbaye, Aarẹ Adetola Emmanuel-King ti sọ pe aṣeyọri nla ni oludije sipo ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Ọnarebu Adesola Ayoola-Elegbe ṣe ninu eto idibo to kọja.

Aarẹ Adetola ni eto idibo to waye lẹkun idibo Rẹmọ lopin ọsẹ to kọja fi han pe awọn araalu nifẹ obinrin naa, lori awọn ipa to ti ko kaakiri agbegbe naa.

Ninu atẹjade ti Aarẹ Adetola fi sita laipẹ yii, o ni itan manigbagbe ni Ọnarebu naa fi silẹ, nitori pe asiko ti awọn ara ilẹ Rẹmọ n foju sọna fun aṣaaju ni wọn dibo yan an.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI