Ijoba ipinle Ogun fee ti Banki GTB pa o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 20, 2017

Ijoba ipinle Ogun fee ti Banki GTB pa o



Ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun ti n gbero lati ti okan lara awon gbajumo Banki lorileede Afrika paapaa lorileede Naijira, iyen Guarantee Trust Bank pa nitori aisan owo ori to ye ki won san lasiko fun ipinle naa.

Gege bi AWIKONKO se gbo, nigba tawon osise ajo to n gba owo-ori nipinle Ogun, Ogun State Internal Revenue Service, OGIRS de ogba Banki naa ni won ti ranse pe alabojuto e lati yoju si won.

Won so pe bi okunrin naa taa foruko bo lasiri se yoju si won, ti won so fun un pe iye owo-ori ti won maa san lodun yi ree. Bi okunrin naa se gba iwe naa yewo, to si ri iye ti won ko sibe lo sare daa pad ape kii se tawon nitori pe owo naa ti poju.

Ibinu ti won ni okunrin alabojuto naa fid a iwe owo-ori naa pada fun won, lo bi awon osise ijoba ajo to n gba owo-ori naa ninu, eyi to si je kawon naa le iwe pe won ko lati san owo ori, iyen ‘NOTICE OF NON-COMPLIANCE WITH TAX LAW’ si enu ona Banki naa.

Ninu iwe alemode ti won le naa ni won ti so pe Banki naa ko lati tele ofin ilana ajo naa, eyi to seese ki won foju wina aibowo fun ofin naa tabi ki won san owo itanran. Won ni won ko leto lati yo iwe naa kuro tabi won faa ya nitori o lodi sofin.

Gbogbo akitiyan AWIKONKO lati ri awon alase Banki naa lo ja si pabo nigba tawon osise Banki naa ko gba wa laye lati ri won ba soro, iyen lati foro wa won lenu nipa igbe ti won n gbe lee lori.

Bi e o ba gbagbe, lose to koja ni ajo OGIRS yi lo ti awon Oteeli bii mefa kan pa niluu Abeokuta lori oro owo-ori yi, nigba ti won so pe milionu lona eedegbeta naira ti won ni ijoba ipinle Ogun n le lari ri lori owo-ori.

Leta ti ajo OGIRS le mo enu ona GTB
Awon oteeli toro naa kan ni Daktad, Royal Pavilion, Adesba, Wenby’s, Courtyard Marquee ati Ceasars. Ohun taa gbo ni pe, awon to ni oteeli naa ti gbe ijoba ipinle Ogun lo sile ejo lojoru Wesde ose to koja lori iwe owo ori ti won mu wa fun won, eyi ti won ja kule.

Lojobo Tosde ni ijoba ipinle Ogun pase pe kawon osise naa pase pe ki won lo tilekun awon oteeli naa pa digba ti won maa fi ri owo naa san.

Gege bi eni to lewaju iko tijoba yan lati lo tilekun awon oteeli naa se so nigba to n bakoroyin wa soro nilu Abeokuta se so, Ogbeni Akintunde Fadare so pe ijoba ti fun awon alase oteeli naa ni ojo gbogboro lati fi san owo naa, sugbon awon eeyan naa ko lati tele ase ijoba, ti won si n se nkan to wu won.

Akintunde so pe lati odun 2015 lawon ti n bawon eeyan naa soro pe ki won san owo ori won, sugbon titi di asiko yii, won ko lati san owo naa. Okunrin naa so pe orisirisi leta lawon ti fi ranse si won lati fi ro won, sugbon won o dawon lohun.

Alabojuto oteeli Adesba, Ogbeni Sodeinde David so pe iro ni awon ajo naa n pa pea won ko san owo ori kokan. O ni kootu ko so pe ki ijoba ipinle Ogun ti awon oteeli pa.
O so pe bukata owo ti ijoba ipinle Ogun labe Asofin Agba Ibikunle Amosun gbe le awon lori ti po ju iye owo to n wole fawon lodun lo. Okunrin naa tun so pe itiju ti ajo OGIRS fun awon lori oro naa le je kawon padanu awon onibara to po.
Nigba to n soro lori idajo ti kootu da lojo naa, o so pe kootu ko pase pe ki ijoba ipinle Ogun lo ti awon oteeli pa, bi ko se pe ki won lo gba awon ohun-ini towo e to iye ti won ni won je won, tawon ileese amohunmaworan OGTV atawon oniroyin kan naa si wa nibe lojo naa.
Sodeinde ni iyalenu lo je nigba ti ileese telifisan OGTV n gbe iroyin naa jade to si je pe ijoba ni won gbe leyin. O so pe, kii se gbogbo nnkan to sele ni kootu nileese OGTV gbe safefe nigba ti won n ka iroyin.
Nigba to n ro ijoba lati boju aanu wo awon oteeli naa, o so pe, o seese kawon tun pada lo sile ejo, nitori pe, eto oro aje orileede yi ti ko lo deede ko je kowo wole daadaa fawon.
Ninu iwadi ti AWIKINKO se lo ti rii pe, lara awon oteeli ti won tip e naa ko tii sise titi di asiko ti a n jabo iroyin yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI