NKAN DE O: Alaga Kansu ran awon toogi lati lu awon Parakoyi oja lalubami - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 19, 2017

NKAN DE O: Alaga Kansu ran awon toogi lati lu awon Parakoyi oja lalubami

Afaimo ki wahala to n sele labele ni Ilugun nijoba ibile Odeda nipinle Ogun ma di nkan ti agbara ko ni ka mo, nitori bi won se ni alaga idagbasoke ti won sese yan, Arabinrin Mofoluke Soremekun ko toogi si oja Kila, tawon yen si n lu awon asoju oja ti won pe ni Parakoyi ni ilu kulu.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni Oba Adedapo Tejuoso to je Osiele Egba lo yan awon kan ti won pe ni Parakoyi lati maa mojumo oja, ti won si ti wa nibe tipe.

Sugbon bi won se ni alaga naa dori ipo lo ti gbe igbese lati le awon ti Oba yan naa kuro nibe, eyi lo si faa ti won lo fi awon toogi lo sibe, ti won si fiya je awon eeyan naa, bee naa ni won tun ta okun di Ofiisi tawon eeyan naa n lo.

Gbogbo igbese ni won so pe aeon Parakoyi naa gbe lati ma we je ki oro naa da wahala sile, amo ti won ni Obinrin yi yari mo won lowo, ti won lo n so pe won ti ti oje bo oloosa lowo, o ku baba eni ti yoo bo.

Idi ni yii tawon Parakoyi Orile Ilugun naa fi gbe obinrin naa lo sile ejo Majisireeti eyi ti Onidajo Idowu Olayinka je adajo e lojo kejidinlogbon osu to koja, won ni bi Obinrin naa ko se je kawon ti Oba yan gege bi ofin se se won ko bofin mu, o si n da wahala pupo sile laarin oja Kila.

Sugbon o seni laanu pe ase ti won nile ejo naa pa pe ki nkan maa lo bo se n lo tele ninu oja maa lo, kawon ti asoju Oba yan si maa ba ise won lo titi ti igbejo yoo fi waye lojo ketadinlogbon osu yii, won ni alaga idagbasoke naa ko muu lo, kaka bee won ni leyin ti adajo pase naa lo tun ko awon toogi pada sawon oja naa lati ma se je kawon eeyan naa sise won.

Eyi lo si faa tawon Parakoyi ati awon ara oja Kila as fi aidunnu won han nipa bi won se ni obinrin naa ko tele ase ile ejo, to je pe agidi inu e lo n lo.

Oniroyin wa pe obinrin alaga idagbasoke Ilugun naa, Arabinrin Mofoluke Soremekun lati gbo tenu e pelu nomba e yi, 08034714417.

Oto ni nnkan ta beere lowo e, oto ni nkan to n ba wa so, nnkan to so ni pe omo ogota odun loun, oun ko le so nnkankan nipa esun ti won fi kan oun, nitori abe ileese kan loun wa.

Bee lo tun so pe oun ko gbo pe won gbe oun lo sile ejo, ohun kan to je oun logun ni alaafia.

Bakanna la tun gbo pe awon kanselo merin ninu aeon marun in ti won n ba obinrin naa sise po tun ti gbe Ogun dide si, won ni ijoba adase lobinrin naa n se ni ijoba idagbasoke naa atipe opo nnkan to n se ni ko je kawon tawon n sise papo mo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI