Oro buruku toun terin; Mohammed yagbe sara ni kootu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 19, 2017

Oro buruku toun terin; Mohammed yagbe sara ni kootu

Titi di asiko yi lawon ti won wa ni kootu Majisireeti to wa ni Ikeja ipinle Ekoo si n ranti isele to sele lojo ti okunrin kan, Hussein Mohammed, eni odun mejidinlogoji ti yagbe sara.

Ojoru Wesde to koja yi nisele naa sele lakoko ti won fee da ejo omokunrin naa lori esun pe o ji okada gbe. AWIKONKO gbo pe ojo Eti Fraide, ojo ketala osu yi ni Mohammed n gbiyanju lati ji okada kan towo e to egberun lona ogota, o le egberun meta, 65,000naira gbe, eyi ti won ni owo palaba e segi ni ikorita Aina George, Ilupeju.

Ejo naa ni won fee da kawon eeyan to sakiyesi pe ara Mohammed ko bale, to n wo pako-pako ninu akolo kootu to wa lati gba idajo e. Oro naa yi biri nigba ti won gbo pe Mohammed ya iso kan to ki, iso ni won pe e, sugbon nigba ti won rii ni won too mo pe se lo yagbe sara, bakanna lo tun to sara pelu.

Kia ni Adajo G. O. Anifowose to da ejo naa ti sare so pe kawon eeyan bo sita digba ti okunrin yoo fit un ara e se. Won ni okun ni Mohammed bu si lakoko naa, nitori itiju.

Adajo naa gba ebe Mohammed pelu beeli, o so pe ki won gba beeli mohammed pelu egberun lona ogota, 60,000naira pelu oniduro meji ti won kun oju osuwon, ti won si le jeri won. O wa sun igbejo miran si ojo kejo osu to n bo.


AWIKONKO gbo pe abe afara to wa ni Iyana-Ipaja ni Mohammed n gbe. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI