Asiko Olorun lo dara ju – Baba Ori Oke - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 10, 2017

Asiko Olorun lo dara ju – Baba Ori Oke


Wooli Jeremiah Okunlola
Ojise Olorun nni, Wooli Jeremiah Okunlola topo mo si Baba Ori Oke, ti Ijo The African Church Solution Camp Ground to fikale silu Abeokuta ti so pe kawon omo leyin Kristi duro sinsin ninu Olorun lati le ri aanu ati ibukun gba lodun 2017.

Wooli Okunlola soro yii lakoko to n waasu nibi ipade adura irole to ma n waye ni gbogbo ojo Isegun Tusde, eyi to koja yi, o so pe diduro sinsin ninu Olorun lo le mu ki won ri ojurere gba.

Nigba to n fi ohun osin adie sapeere nipa bi a ti n duro de asiko Olorun, o so pe, “Bi adie ba ye eyin, ojo mokanlelogun lo maa fi saba lee lori ko too le fi pa omo e. To ba ti n ku ojo marun si meta, adie naa ko nii kuro lori aba titi ti o maa fi pa awon eyin e.

“Ko ni kuro lori aba lati loo jeun, tabi mu omi, inu irora lo maa wa to ma maa duro de ojo ti asiko maa fi pe. Asiko naa lo n woju Olorun lati ri aanu gba. Bi adie naa ba sesi kuro lori aba, ko nii pa awon eyin naa.

“Beeyan ba de odo e lati lee kuro, ko nii dahun nitori pe, won wa lati dan an wo ni. Ko si nnkan to le gbe kuro lori aba naa ayafi to ba pa awon eyin e.

“Bo se ye ko ri ninu aye awon onigbagbo niyii, nitori pe lasiko ti adura ba ti fee gba, lawon arekereke ota maa yoju lati dan won wo. Bi eni naa bee ba si sesi ko si pampe ota, yoo tun sese bere adura e lati ibere ni.”

O wa ro won pe ki won ma se wo aago alaago sise nitori pe nnkan to lewu ni, atipe won ko mo nnkan ti iru eni bee ti lo toju bo. O wa fi iwe Orin Dafidi 40:1 nibi ti Oni Saamu ti so pe ‘mo duro de ife Oluwa’ se apeere.

Ojise Olorun naa tun so pe kawon eeyan gbenu kuro lori awon orin igbaani bi “Ko su wa lati ma korin igbaa nni” nitori pe ko ye keeyan maa korin kan soso lo titi. O ni orin ope bii “O sohun titun laye mi ko dawo duro” ni ki won maa ko.

O wa pari iwaasu ojo naa pelu adura pe ki Oluwa ran won lowo lati duro ninu ife re atipe ki Olorun fi orin titun si won lenu lodun yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI