Awon oniroyin nipinle Ogun si n seranti Abiodun Onafuye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 23, 2017

Awon oniroyin nipinle Ogun si n seranti Abiodun Onafuye

Titi di asikoyi lawon egbe akoroyin< NUJ, eka tipinle Ogun si fi n se iranti okan lara won, Abiodun Onafuye topo mo si Jagaban, to jade laye ninu osu kejo odun to koja. Oun ni asojukoroyin fun ileese PM NEWS/THE NEWS nipinle Ogun.

Bo tile je pe ibanuje nla niku naa je fun won lakoko naa, atipe ko tii pe ti enikan naa ku ko too di pe Onafuye jade laye. Eyi lo si faa tawon akoroyin fi bere akanse adura labele won lati gbogun ti iku ojiji.

Abiodun Onafuye, Jagaban
Bo tile je pe okunrin naa ti n saisan tipe ko too dipe o dagbere faye lojobo Tosde, ojo kejo osu kesan odun 2016 nile iwosan kan to wa ni Iseyin nipinle Oyo nibi to ti n gbawosan.

Ohun taa gbo nipe okunrin naa ti wa ni idaduro nileewosan kan niluu Abeokuta fun bii ose kan, ko too dipe o pada sile. Ko juu bi ojo meta to kuro nileewosan naa ni nnkan tun yiwo ko too dipe won sare gbee lo siluu Iseyin fun itoju.

Okunrin naa la gbo pe odun 2006 lo de silu Abeokuta gegebi asojukoroyin fun PM New/The News titi digba to fi ku.
Iwadi tun fi ye wa pe ko pe ti won fi je okan lara awon olootu agba fun ileese naa nisele aburu naa sele.


Lakoko naa ni Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun fi aidunnu e han lori isele naa, to si awon akoroyin ati ebi oloogbe na kedun lori iku e. O si gbadura fawon akoroyin lorile ede Naijiria paapaa nipinle Ogun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI