DaGrin ni awokose mi - Danny Dowsk - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 2, 2017

DaGrin ni awokose mi - Danny Dowsk

Ohun teeyan ba moo se, a fi ko tera mo daadaa nitori bo pe bo ya, igbadun e si n bo lojo kan. Akaimoye awon olorin paapaa awon gbajumo olorin takasufe, iyen hiphop taye n gba ti won lo je pe kekere ni won ti bere ko too di pe aye mo won, lara won ni Oloogbe Michael Jackson, Olamide, Davido, Wiskid, Small Doctor ati bee bee loo.

Dani Dosky
Okan lara awon irawo olorin takasufe to sese n dide bo nipinle Ogun, bo tile je pe o sese bere orin ko tii ju odun marun lo, sibe, ko seni to teti si orin e ti ko ni gbosuba kare fun un, iyen Ayobami Adewunmi tawon ololufe e mo si Danny Dowski ti so pe ogbologb olorin nni, iyen Oloogbe DaGrin lo maa n mu ori oun wu nigba toun ba n gbo orin e.

Danny Dowski lakoko to n ba oniroyin wa soro lose to koja nilu Abeokuta so pe ipele keji loun wa nile eko girama lodun 2012, igba naa loun gbo okan lara awon orin DaGrin to pe ni PonPonPon to si si oun niye lati so pe oun naa fee gbe gba orin.

Odomokunrin eni odun metadinlogun naa so pe bo tile je pe oun sese setan nileeko girama lodun to koja ni, anfaani nla lo tun je foun lati dojuko ise orin naa ni kikun nitori itara toun ni ninu e.

O ni orin kiko ko di oun lowo lati ma se tesiwaju ninu iwe oun toku nitori iwe kika dara pupo, ati pe beeyan ko ba kawe mo ise to ba yan laayo, onitohun ko ni kuro loju kan soso.

Danny Dowski wa ro awon eeyan leka ise orin, iyen awon promota paapaa awon ileese to n gbe awon orin jade, iyen Record Label lati fi oju aanu wo oun, ki won si ran oun lowo lati gbe oun jade, koun baa le mu ayanmo oun laye se.

Bakanna lo tun so pe oun ti gbiyanju lati se awo orin single kan jade pelu ifowosowopo awon ore oun kan, tawon eeyan si n kan sara soun pe ise loun se, atipe koun tubo tera mo.

Ninu oro e, o so pe "Inu mi a dun ti n ba ri eni to le ran mi lowo lati gbe mi sita.

"Ti n ba wa nibi to dake je, tabi ti n ba laarin awon ore mi, mo kan maa n ri pe orin yen kan n wa ni, lesekese ni maa mu bairo ati iwe, ti maa fi ko sile ki n ma baa gbagbe.

"Igba miran wa to je pe ti m ba koja nibi ti won ti n korin, ilu atawon eroja orin ti won n lu si yen, mo le loo lati fi se agbekale orin temi naa.

"Mo ti wo ile igbohunsile leekan pelu awon ore mi, mo si ti se awo orin kan jade, iyen single tawon eeyan si n kan sara si mi pe mo gbiyanju. Nitori "Street Thought" ni mo pe lati fi so awon nnkan to n sele laarin awon odo nigboro, iyen ni pe igboro gbona."


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI