Ibrahim tun ko sawon olopaa lowo leekeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 21, 2017

Ibrahim tun ko sawon olopaa lowo leekeji

Iwa ko nii fi oniwa sile atipe ko si bi a o ti se ebolo ti ko nii run Ogbe, eyi lo ni ibamu pelu odomokunrin kan, Ibrahim Akinola tawpn olopaa fi sile laipe yii, to tun pada loo jale.

Gege bi AWIKONKO se gbo, lojo Isegun Tusde ose to koja nileese opaa ipinle Ogun rowo to Ibrahim lagbegbe Orimerunmu ni Mowe, ipinle Ogun.

Ibrahim odaran
Ohun ti a gbo ni pe laaro ojo naa ni won so Ibrahim atore e kan ti yen ti na papa bora lo digun ja Ojupeju Joseph lole, ti won si gba owo to to egberun lona igba naira lowo e.

AWIKONKO gbo pe se ni Ibrahim sa okunrin naa, iyen Joseph ni ada niwaju ori lakoko ti won jo n jijakadi, ti won si gbe owo naa ati telifisan alara ogiri e salo.

Ariwo ti won so pe Joseph n pa pe won ti fee pa oun lo ma kawon to wa nitosi ile e ji, ti won si ranse sawon olopaa. Loju ese ni won so pe DPO ekun Mowe, Ogbeni Charles Ebhuoma lewaju awon olopaa lati lo koju ija si won.

Bawon olopaa se de pelu oko won ni won ni Ibrahim store ti n gbiyanju lati salo, sugbon ori talo Ibrahim pelu telifisan to gbe dani nigba ti enikeji e na papa bora pelu owo ti won gba naa.

Agbenuso olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi so pe loot ni atipe awon ri lara awon eroja oloro ti won ko dani ati eru ti won ji  gba lowo Joseph bo tile je pe enikeji e juba ehoro.

Abimbola je ko di mimo fawon akoroyin pe bo tile je pe ko tii pe ti won fi Ibrahim sile logba ewon lori esun idigunjale ti won fi kan, eyi ti ile ejo ran an lo sewon, sibe ejo miran tun si wa ni Kootu ti Ibrahim n je lowo nipa iwa idigunjale naa lo si da le lori.

Agbenuso naa wa fi kun oro e pe Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa ti pase pe ki won gbe Ibrahim lo sodo awon olopaa FSARS lati le tesiwaju ninu ise iwadi won, ki won si rii daju pe ore Ibrahim to salo naa si ko si pampe won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI