Talo ye ka bawi??? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 24, 2017

Talo ye ka bawi???

Bo tile je pe ijoba apapo, ipinle ati ibile orile ede yi ko ni orin meji ti won n ko ju senji (Change) lo, ti won si n so pe awon fee dekun iwa ibaje laarin awon to di ipo mu lawon eka ile ise ijoba, paapaa awon osise ijoba.

Bi ijoba to wa lode yii se n pariwo senji naa to, ti won si mura kankan lati yo awon oga agba leka osise kookan ti won si n fi awon mi in ti won ro wipe won le sise naa daadaa ju ti won lo ropo won, lati le mu ipinu won se, ki orile ede yi naa si le gun oke agba.

Sugbon on, se lo dabi eni wipe ona ti ijoba fe gba lati dekun iwa ibaje lorile ede yii ko ju ti ona ti awon wobia alajebanu osise n gba lati se owo ilu moku-moku. Bi a ba beere lowo "A" wipe kini itumo senji ti wo n pariwo, ko si nnkan meji ti yoo so fun un yin ju wipe iwa isowo moku-moku gbodo dinku lawujo wa lo. Bakanna an le o se gbo lenu "B", "D" ati oniruuru awon eniyan kaakiri.

Iyalenu lo ma n je lopo igba bi e ba de ile ise ijoba yala lati lo se iwadi, tabi sise, tabi gba foomu, tabi lo fun abewo, tabi lo fun ayewo, tabi lati lo gba itoju, ti e ba n gbo ti won n so wipe "Not On Sit", e ma je ko ya yin lenu wipe eni ti e fee ri ko si lori ijokoo lo n je bee.

Ti won ba so fun un yin wipe ki e pada wa, e ku oriire niyen, ki e fi ope fun Olorun aseda loke nitori pe eni ti o so wipe ki e pada wa yala ojo keji ni tabi ose kan leyin naa je eeyan Olorun, nnkan ti o wopo ti won yoo so fun un yin ni wipe, ki e jokoo, oga ko ni pee de.

Bi e ba si jokoo ti e o bikita lati wo aago, e tan ara yin ni, nitori wipe e o ni mo igba ti e fi maa lo wakati marun un lori ijokoo. Bi o ba je eni to feran lati maa wo aago loore koore ni, nigba ti iru eni bee ba wo aago titi to ba suu, ko ni mo igba ti yoo gbagbe sun lo. Se e si mo wipe oorun baje pupo, ko si ibi ti ko ti le baa eeyan ni alejo.

Ko si eka ile ise ti iwa yi ko tii jeyo. "Bo ti wa ni liki, bee naa lo wa ni gbanja" gege bi won ti se ma fi n dasa. Bi iwa buruku yi ti n gbooro si ni eka ise adani, bee naa lo je wipe ko dinku ni eka ile ise ijoba kaakiri, paapaa ipinle Ogun.

Ni orile ede Amerika, tabi ki a so wipe ile Alawo funfun, bi enikan ba wa osise kan de ofiisi e, ti awon to wa nibe si so wipe eni naa ko si lori ijokoo lai ni idi kan pato, ko si nnkan meji ti won yoo se ju ki won gbe foonu, ki won si pe awon oga agba patapata ile ise naa lati fi ejo iru eni bee sun un.

Ko seni to too da asa wipe ki o wa lenu ise, ki o si dide lati lo se nnkan ti ko ba ofin ise naa mu. Iru eni bee, bi ko ba fi ewon sere, yoo gba leta ifisesile, iyen sack letter. Bi ko ba si gba leta ifisesile, ohun ti oju iru eni bee yoo rii, nile aye e, ko tun ni da iru asa bee mo titi ti yoo fi feyinti nidi ise naa.

Awon ibi ti asa naa poju si ni ile iwosan, paapaa gbogbo awon ile iwosan to je ti ijoba patapata. Mi o ba ni ka fi eyi se apa kin-n-ni nitori asiko ko ni le gba wa lati yannanaa awon eka ise ti iru iwa ibaje asa palapala bayi ti n jeyo.

Bi e ba de ile iwosan ijoba, paapaa nipinle Ogun, opo dokita leka ise otooto lo wa nibe, bi a ti ni dokita oju, bee naa la ni ti awon alaboyun, awon omo keekeeke ati bee bee lo. Ti ijoba si gba won lorisirisi lati le maa se itoju awon to ba fee gba iwosan. Ijoba ko gba dokita kan soso si eka ise kan ni awon ile iwosan ijoba kaakiri.

Bi awon dokita se po to, ko si igba tabi akoko ti e lo lati lo ri dokita yala fun ayewo tabi itoju, awon noosi ti won o mo kulekule oro ilera ni won yoo maa da yin lohun, iyen ti won ba daa yin lohun niyen, ti won o so fun un yin wipe dokita o si lori ijokoo, awon mi in le so fun un yin ki e pada wa tabi ki e duro.

Aaye ko gba wa lati maa daruko awon ile iwosan ijoba atawon ile iwosan aladani naa sugbon aaye wa fun un yin lati beere bi e ba fee mo. Iwadi ijinle ti a se lo je ka mo awon nnkan to n lo lawon ile iwosan naa, ko daa, opo awon eeyan lo ti padanu emi won latari awon iwa aibikita yii.

Bi e ba fi ehunu han si awon dokita tabi ile iwosan naa, awon noosi tabi awon osise ni won yoo maa so fun un yin wipe se e ko ri ile iwosan miran nile ki e too ya si odo won ni, nigba to je wipe emi awon eniyan ko jo won loju.

Bi e ba si wo awon noosi elenu guluso won yii, ki ijoba tabi awon aladani too gba won si ise, ninu leta iwose ti won ba ko le o ti ri orisirisi ileri wipe awon yoo sise won daadaa, awon yoo bojuto gbogbo nnkan to ba wa ni ikawo won.

Pabanbari e ni wipe awon yoo sise won koja ibi ti awon to gba won sise ko lero. Yes ke! Bi asa oloyinbo, lara awon ileri won naa ni pe awon yoo maa sun, se gbeborun, se ayanju ran kaakiri lenu ise won. Won o ni nnkan meji ti won n se lenu ise won ju ayanjuran ati aheso oro to ti ku lo. Awon lo maa n ri elepon kan.

Ko si igba ti e wa dokita de ile iwosan ti e o ba a lori ijokoo re, bee kii se wipe o wa lenu ise kan ni pato. O se ni laanu wipe ko si aaye lati daruko dokita ati ile iwosan ti awon irufee iwa buruku yii poju sii, sugbon awon ti o ba ti ni iriri iru nnkan bayii yoo mo nnkan ti a n so ati awon ibi ti o ti n sele.

Bi eniyan to wa ni imajensi ti ko tete ri dokita lati yoju si ba gbabe ku, erin lawon noosi yoo maa rin, ti won yoo maa so orisirisi oro ti ko se e gbo seti bii "se igba akoko ti won maa gbo pe eniyan ku niyii, abi e se wa n sunkun bi omo ikoko ti won sese gba omu lenu e".

Ijoba paapaa bi won se n gbiyanju lati mu adinku ba awon ona ti awon araalu yoo maa so awon oro abuku ba won, won o se abojuto awon ohun to ye ki won se abojuto e daadaa. Ole, imele lawon ti ijoba yan lati maa mojuto awon irufee awon ti won n hu awon iwa yii.

Bi ijoba ba gbe igbimo kan dide wipe ki won maa yoju sawon ofiisi kaakiri lati maa mo awon nnkan to n sele nibe. Bi awon yen naa ba de ibi ti won ti lo se ayewo, ti won ti fi oti elerin dodo to tutu daadaa se won lalejo pelu ounje aladidun, ko si nnkan meji ti won n se ju ki won gba nomba ero ibanisoro won lo, lati le so fun won sile igba ti won a tun pada wa, fun won lati le mura sile.

Ohun ti won maa je ko je ki won gbon. Awon igbimo abewo ti ijoba paapaa n yan lati maa se abewo awon eka ise kaakiri lo je wipe won o mo nnkan meji ju owo lo. Asa oga ko si lori ijokoo yii ye ki o di ohun igbagbe lakoko senji ti a n pariwo yii.

Ibeere to wa ye ka bi ara wa ni wipe talo ye ka ba wi ninu ijoba, igbimo ti ijoba n yan lati se abewo ati awon osise to je wipe won kii sise won bii ise, to je wipe gbogbo igba ni won kii si lori ijokoo lakoko to ba ye ki won wa nibe?

Ire o.

4-November-2015

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI