Aye ma le o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 23, 2017

Aye ma le o


Joseph lu baba onile e daku

Bo tile je pe titi di asiko yi lawon olopaa ipinle Ogun si fi n sewadi lowo, sugbon sibe, gbogbo awon to gbo sisele naa ni won n so pe a fi ki won dajo iku fun Joseph Isiwele ti won fesun kan pe o lu baba onile e, Oloogbe Omotayo Sanda daku lagbegbe Itoki nipinle Ogun.

Komisana olopaa, Iliyasu
Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni egbon Joseph, iyen Michael Isiwele lo lo ko iyepe ni eyinkule ile ti won yagbe, to si ko o lo si ile ti baba won n ko lowo, nitori won so pe agbara ti ba iwaju ita ile naa je.

Won lojo Satide Abameta to koja lo lohun ni won ni Michael ko iyepe naa ni nnkan bi aago mefa si meje aabo ale, sugbon akobi baba onile naa, Taiwo Sanda lo ri Michael lakoko to n ko iyepe naa, to si beere pe owo talo ti gbase.

Ninu oro Taiwo, o so pe “Nigba ti mo de lati ibi ti mo ti n kose ounjeni nnkan bi aago meje ale, mo ba Michael nibi to ti n ko iyepeleyinkule ile wa, mo beere pe ki lo fee fi se, sugbon ko dami lohun, o kan rerin ni.

“Nigba ti baba mi de laago mejo, o beere pe talo ko iyepe nibe, mo wa so fun won pe Michael ni. Baba mi lo si yara won, o si lo kilo fun won nibe pe ki won sora won, nitori pe won ti n gun igi koja ewe.

“Nibi ti won ti n soro naa ni Joseph ti sare wa, to si bere sii pariwo mo baba mi, bee lo tun n gba won lese titi ti won fi subu lule ti won sib ere sii pofolo. Mo sare wonu ile lo bu omi wa nigba ti mo ri bi won se n se, sugbon nigba ti a rii pe oro naa ti koja oju ti a fi n wo, la fig be won lo si osibitu to wa nitosi ile, sugbon awon yen so pe ki a gbe won lo si jenera.

“Joseph lo pon won seyin nigba ti a bere sii wa moto lati fi gbe won, sugbon nigba toro naa yiwo to di pe baba mi ko mi mo, lo ba ju won sile, to si salo. Won ti gbe maami kuro nile lo si odo awon eeyan wa nitori ironu.”

Okan lara awon molebi oloogbe naa, Joseph Akinsola so pe ni nnkan bi aago mesan aabo ni won pe oun, nigba toun de be, loun rii pe baba naa ti ku. Okunrin naa loun loun lo sodo Baale lati lo fi ejo sun, atipe oun fee ya moto e, sugbon o ni moto oun ti baje.

Alukoro olopaa ipinle Ogun so pe looto lawon ti gbo si isele naa sugbon iwadii si n lo lowo, o so pe Michael ati Edward si wa ni akolo awon ti won n foro wa won lenu wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI