Iyan, Obe Egusi ati Eja-gbigbe la fi n bo Olumori – Baale Idi-Ori - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 14, 2017

Iyan, Obe Egusi ati Eja-gbigbe la fi n bo Olumori – Baale Idi-Ori

Ilu Idi-Ori kii se ilu kekere ti won sese da sile, odun 1834 ni won ti da sile. Ijoba ibile Abeokuta North lo si wa nipinle Ogun. Sugbon nitori ayeye odun Idi-Ori to waye lojo Abameta Satide to koja yii, Baale Adegboyega to je Baale ilu naa ba AWIKONKO soro nipa idi ti won fi n bo igi Ori, eyi ti won fi so oruko ilu naa.

AWIKONKO: Nje a le mo yin, pelu ipo ti e di mu?
BAALE: Oruko temi ni Dauda Adedeji Adegboyega Ajala. Emi ni Baale Ilu Idi-Ori nijoba ibile Abeokuta North. Odun 2010 ni mo je Baale.

Baale Idi-Ori, Oloye Adegboyega
AWIKONKO: Nje e le so die fun wa nipa itan isedale Idi-Ori?
BAALE: Itedo yi je ti Owu. Ni odun 1834, nigba ti awon baba nla wa kuro ni Orile, ti won de ilu Egba, Idi-Ori ni ileto akoko ti won koko de lati sise oko. Awon meji ni won koko wa, ise ode lo gbe won wa. Ti won ba ti fee sise ode tabi ise oko, won a bo aso won, won a fi ko si ara igi kan, igi yen ni a n pe ni Ori, eyi ti a fi so oruko ilu yii. Abe igi yen ni won maa n joko si gbategun. Leyin igba die, won gba a lero lati lo pe awon ara won toku lati wa pago sibe, lati din wahala lilo bibo ku. Sugbon ki won too lo, won bu iyepe ibe dani, won si lo beere lowo awon onifa boya ibe dara lati gbe. Igba ti won gbe ifa sanle, ifa so pe ibi ti won wa yen gan an, ilu won lo je, atipe igi ti won n fi aso ko si iyen, igi Ori loruko e, nitori naa ki won maa bo igi na lodoodun, nitori pe, iya olomo wewe ni igi yen.

AWIKONKO: Abule meloo lo wa labe Idi-Ori.
BAALE: Abule marundinlogbon lo wa labe Idi-Ori. Onikaluku lo si ni Baale ti e.

AWIKONKO: Kini anfaani igi Ori yi, ti won fi n bo. Bawo ni won se n bo?
BAALE: E se. Iyan, Obe Egusi ati Eja gbigbe ni ifa ni ki won maa fi bo igi Ori yi nigba naa lohun. Kii se nnkan eleje ni won fi n bo. Ti won ba ti fee bo, onikaluku a gbe iyan lati ile won lo sidi igi naa, ti won a si beere nnkan ti won ba fe lowo e. Nnkan ti a ba ni pe, bi eeyan ko ba ri omo bi, ti o ba de idi igi yi, to ba bo o, to si beere omo lowo e, leyin odun kan, o gbodo gbe omo naa pada lo fi dupe, iyen ni pe igi to n gbo adura ni. Ko si nnkan naa ti won n beere lodo igi yii ti won ko ni ri gba. Tori e lo se je pe to ba ti n di igba odun, a ma n paaro aso funfun ti a fi yi lara, iyen laa n so pe iya ti paaro aso e. eekan lodun ni a maa n paaro aso e.

AWIKONKO: Kini Pataki ayeye odun Idi-Ori atipe ki lawon idagbasoke ati anfaani to ti jade lati ara ayeye yii?
BAALE: Mo ti so leekan pe, nnkan ti a ba lowo awon Baba nla wa ni, a o si gbodo je ko parun. Lara awon anfaani e ni isokan gbogbo omo Idi-Ori ati idagbasoke ilu ni a fi n se. Ko ri bayii tele ki n too di Baale, sugbon latigba ti mo ti de, mo ti mu opolopo olaju wo, eyi to je kawon eeyan tewogba. Kii kuku se pe oogun ni a n se. iyan, obe egusi ati eje gbigbe ni a fi n sodun naa.

AWIKONKO: A ri awon ilu to je pe won o dagba to ilu Idi-Ori sugbon ti won ti ni idagbasoke to see toka si, ki lo de ti iru eyi ko ri bee ni Idi-Ori?
BAALE: Ibeere to dara ni. Mo dupe lowo yin. Iyen lo mu wa lati dide dide pe ka ja fun eto wa nitori pe gbogbo awon ilu to je pe nigba ti won jo de ibi, awon bii Ibogun, Akinale, Onigbedu, Sango, Ifo ni won wa ni Idi-Ori tele ko too di pe onikaluku won kuro lati lo tedo sibo mi ran. Ki lo si faa? Idi e ni pe, nigba ti won da oko titi, ti won ko fi bee ri ere to po. Ti won sakiyesi pe ile yen ko dara fun koko lati bu yaari, eyi lo mu ki won kuro lati lo sibo miran. Nipa ti idagbasoke, awon ilu ti mo n daruko yi, oju ona ni won wa, sugbon ti ijoba ba fee so ona, ibe ni won n sise gba. Nnkan to fa ifaseyin ba Idi-Ori nipe ko bo si oju ona, a maa ya wole ni. Sugbon ni bayii, a ti n rawo ebe sijoba ipinle Ogun lati foju aanu wo wa lati ranwa lowo. Eleekeji ni pe, awon ajagungbale ko je ka gbadun bo tile je pe wahala naa se se n dinku ni. Opo awon eeyan ni won ti wa wipe awon fee wa da ile ise sile, sugbon ti won ba de, awon ajagungbale lo maa da won lowo ko. Sugbon pelu ofin tijoba gbe kale, won ti dinku. Mo si gbagbo pe laipe, itesiwaju yoo de. 

AWIKONKO: Bawo ni yiyan Baale se bere atipe ki lo faa ti ko tii si Oba nilu Idi-Ori?
BAALE: Latigba ti won ti tedo sibi ni won ti n yan olori bo tile je pe ko si Baale, nitori pe won fowosowopo. Eni ti o ba si dagba ju lo maa n se olori. Nigba ti oju bere sii la lawon eeyan wa wo o pe o ye kawon yan Baale, to si je pe ijoba naa ti da si. Itu merin lo wa nibi, ti itu kan ba papoda, itu miran a dide lati je, kii se pe won gbogun tira won ki won too le de ipo naa. Awon ara itu kookan ni won maa faayan kale. Ni ti oro oloba de, nnkan to je mi logun ni idagbasoke kii se ipo tabi oye. Leyin ti mo de ni mo se ina ti mo si rii pe omi wa kaakiri. A ti n gbe igbese lori oro osibitu ati ile eko. Ijoba la n ro lati tete da wa lohun.

AWIKONKO: Nje e o lero pe bi e se fi aaye gba awon ajoji lati maa ni Baale ti won ko le sakoba fun yin lojo iwaju.
BAALE: Ko le ri be. Awon ajoji to wa nilu, won po, to si je pee de otooto ni onikaluku n so. Ti a ba fee se ipade gbogboogbo, gbogbo wa o kan le kori jo, a nilo asoju, eyi lo faa ti a fi woo pe kawon naa ni Baale ti won. Latigba ti a ti bere, a o tii kabamo, a o si ni kabamo.

AWIKONKO: Ki le fee so nipa igbese ti ijoba ipinle Ogun n gbe bayii lori bi won se so pe awon lawon yoo maa sakoso oro oloye ati jije Oba bayii nipinle Ogun?
BAALE: Boya e o gbo alaye ijoba daadaa, ko si bi won se fee se, ni gbogbo ileto kaakiri, won ni Olori awon Oba. Oba lo si le fi Baale je, leyin toun bay an Baale ti e ni ijoba sese le fowo si lati fun ni iwe eri. Ijoba ko le deedee gbera lati so pea won n lo si ileto kan lati so pe awon feeyan Baale tabi Oba, to ba ri bee, o ti di oro oselu niyen.

AWIKONKO: Kini oro amoran yin fawon araalu paapaa awon omo Idi Ori?
BAALE: E se pupo. Oro amoran mi ni pe Oro amoran mi ni pe bi nkan ti le wu ko le to lasiko yii, ki a jo fori ti nitori pe leyin okunkun biribiri, imole a tan, Oluwa a ran wa lowo. Fawon omo Idi-Ori, e je ka tubo gbaruku ti asa wa, ki o ma baa parun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI