Gbogbo eto lo ti to pari bayii lori ayeye odun ilu ile Afrika to fee waye nilu Abeokuta tii se olu-ilu ipinle. Gege bi Komisana foro asa ati irin ajo afe nipinle Ogun, Bashorun Muyiwa Oladipo se so, o ni ogunjo si ojokejilelogun osu kerin ni ayeye naa yoo waye nilu Abeokuta.
Komisana foro Asa ati Irin-Ajo Afe |
Komisana so pe ono ara oto ni ayeye odun ilu todun yi fee gba waye
nitori pe opo awon eeyan lo n bo kaakiri ile Afrika ati paapaa awon eya kan
lorile ede Amerika naa n bo lati wa kopa nibi ayeye naa.
O ni nigba tawon n si aso loju eegun lodun to koja, ni gomina ipinle
Ogun, Ibikunle Amosun ti tenumo o pe odun ilu ile Adulawo, iyen African Drum
Festival lawon fe maa se, leyi ti yoo ma a pe orisirisi awon otokulu nile
Afrika wole silu Abeokuta.
Komisanna so pe ona ara oto ni ayeye odun ilu ti odun yii maa gba waye
nitori pe awon n reti awon alejo lati ilu Oyinbo, atipe won ti ranse sawon pe
won n bo lati wa wo bo se maa lo.
O ni opo orileede ni won ti gbosuba kare fawon leyin ayeye todun to
koja, eyi si se e toka si gege bi aseyori nitori pe awon ara ile Amerika naa ti
so pe awon n bo lati wa kopa nibi ayeye odun ilu todun yii.
Nigba to n soro lori asa ati ise nipinle Ogun, Komisanna so pe adie n
laagun sugbon iye ara e ni ko je ko han somo adamo nitoripe bi ojo se n gori
ojom ti osu n gori osu, ni oju n la si ti imo tuntun n sokale wa bo tile je pe
akitiyan naa ko tii fojuhan sita gbangba.
Omoba Muyiwa so pe laipe, gbogbo wahala tawon n se lori wipe ki asa
ipinle Ogun ma baa parun, sugbon ko le rinle si. Bee lo kanminu pea won eeyan
nipa olaju ti gba asa oyinbo ju bo se ye lo, eyi to faa ti won fi pa asa
isembaye ti wa ti. O lawon babanla wa lo ti se asise nigba tawon Oyinbo de, ti
won si je ki asa oyinbo gba asa tiwa-n-tiwa lowo won.
O loo soro lati so pe a fee fi odun merin se atunse asise ogorun odun
eyi tawon babanla wa ti se. Diedie ni igbese tawon n gbe lori e, ati paapaa,
nipa ede, o ni ko seni to fee so ede abinibi wa mo, to si je pe ede oyinbo la
fee so, o ni eyi ko bojumu to.
Bakanna lo tun so pe ise ko duro leka eto afe nipinle Ogun lori bi owo
se tubo le maa wole si ju tele naa, nitori pea won orileede kan wa to je pe eto
irin ajo afe nikan ni won fi n gbera ti won o si je ko parun, o waa mu da awon
omo ipinle Ogun loju pe, igbadun ara oto ni won yoo maa je nigba ti ise ba
pari.
Oladipo wa rawo ebe sawon
araalu, paapaa, awon omo ipinle Ogun lati tubo gbaruku ti asa ati ise ile yii,
ki orison wa ma baa parun.
No comments:
Post a Comment