Chigbo to n fipa ba aburo iyawo e sun ti wa lago olopaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 23, 2017

Chigbo to n fipa ba aburo iyawo e sun ti wa lago olopaa

Boroboro ni Kingsley Chigbo nka ni tesan olopaa to wa ni Eleweran, Abeokuta lose to koja nigba ti asiri e tu sita pe aburo iyawo e, omodun metala lo n ko ibasun fun karakara.

Chigbo re o
Gege bi AWIKONKO se gbo, Chigbo, eni odun marundinlogoji lowo palaba e segi ni ojule kejidinlogun Asikolaye Gasline, Ijoko Ota, nigba ti won so pe enikan lo fi ejo e sun ni tesan olopaa to wa ni Ota

AWIKONKO gbo pe Obinrin kan ti won pe oruko e ni Peju, to je oludasile ajo kan to maa n daabo bo awon omode nilu Abeokuta lo loo fe ejo Chigbo sun ko too di pe DPO Olopaa, Akinsola Ogunwale lewaju awon olopaa lati loo fowo ofin mu.

Nigba to n soro, Arabinrin Peju Osoba so pe okan lara awon osise oun lo loo se idanilekoo nile eko Bannis College Ota, o ni leyin idanilekoo naa ni omokekere naa lo baa, to si salaye fun wipe oko egbon oun maa n ba oun lasepo pelu agidi.

O lomo naa so pe se ni Chigbo maa n hale mo oun pe ojo toun ba so sita loun maa ri aye mo, eyi lo si ko iberubojo baa ti ko fi le soobu sita. Bakanna lo lomo naa n gbon lohun nigba to n soro naa.

Agbenuso olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n jeri soro naa so pe lesekese ti Komisana awon ti gbo lo ti pase pe ki won maa gbe bo ni Eleweran lati tesiwaju ninu iwadi.

Abimbola ni bo tile je pe Chigbo ti jewo pe looto ni, to si so pe ise esi nii, o ni Komisana ti dari ejo naa lo si eka olopaa to n ri soro fifi omo se owo eru lati tesiwaju ninu ejo naa.

Bakanna lo tun fi kun pe Chigbo ko ni pe ti yoo fi foju bale ejo. O wa gbawon araalu lamoran lati maa bojuto awon omo won daadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI