Gege bi AWIKONKO se gbo, Adigun John
ti inagije e n je Akoto ati Idowu Kalejaye lawon odomokunrin naa nigba ti won
won so pe ileese buredi kan ni won lo ja lole.
Adigun ati Idowu |
Won ni nise ni Adigun ati Idowu wonu
ileese buredi naa bi eni to fee wa ra oja, sugbon gbogbo bi won se lojo naa
lawon to wa nibe ko tete fura.
Okan lara awon onibara to wa ra
buredi laaro ojo naa, Bose Agboola ni won koko ji poosi e yo, ti won si ko
egberun meedogun naira.
Ko pe sigba naa ni won tun ji
egberun meji naira ati foonu Nokia to je ti eni to nile ise buredi naa, iyen
Ogbeni Taiwo Ogunyemi. Gbogbo bi won se n se eyi ni won n bawon to wa nibe
dapara lati ma je ki won fura.
Bi won se ji awon nnkan yi tan ni
won ni Idowu ti jade sita to si fe maa salo, sugbon lakoko naa ni won ni Bose
ti fura pe ko si owo lara oun mo, ko too di pe o pariwo sita.
Ibi ti won ti n pariwo yi ni won ni
Adigun ti fa ibon yo sita pe oun yoo yin fun eni to ba pariwo, eyi to ko
jinijini bawon to wa nibe. Okan lara awon to n koja lo to gbo oun to n sele lo
yoju loju ferese lati woran.
Nigba to rii pe aaye si sile lati mu
okan ninu won lo fi yo kelekele wole to si diro mo Adigun to gbe ibon dani.
Nine ni won ti bere sii jijakadi toro naa si di boolo o yago.
Leyin-o-reyin ni eon mu awon mejeeji
bale ko too dipe won ranse sawon olopaa lati wa ko won lo si tesan won nitori
won ko fee se idajo lowo ara won bo tile je pe won ti kona iya fun won.
Agbenuso olopaa, Abimbola Oyeyemi
nigba to jeri sisele naa so pe DPP Ogijo, iyen Tijani Muhammad lo lewaju awon
olopaa lati lo ko won.
Komisana olopaa, Ahme Iliyasu ti wa
pase pe kawon olopaa FSARS ko won lo lati lo foro wa won lenu wo fun iwadi ni
kikun. O wa gbawon araalu lamoran pe ki won dekun lati maa se idajo lowo ara
won, sugbon ki won maa feti awon olopaa to awon isele to ba je mo iwa odaran
ladugbo won.
No comments:
Post a Comment