Awuyewuye lori isinku Moji Olaiya - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 19, 2017

Awuyewuye lori isinku Moji Olaiya

Gege bi asa Musulumi nipa bi oku ba ku, ojo ti oku ba ti ku lo gbodo wole, ayafi to ba je pe o ti to owo asale ki oku too ku lo maa di ojo keji, sugbon ibi ti oro isinku gbajumo osere tiata to ku lana Ojobo Tosde, Moji Olaiya n lo bayi ni ko seni to ye.
 
Moji ati omo e, Adun
AWIKONKO gbo nipe Ilu Canada ni won fee sin in si, sugbon ti omo e, Adunola Farombi se so pe ko jo, a fi ki won gbe iya oun pada wa sile foun lati ri, o ni ko si nnkan to kan oun nipa asa wipe won kii sin oku lojo keji.

Adunola so pe bi won ba sin iya oun lai je koun ri, gongo a so, akutupu a wu, wahala nla a sele, bo tile je pe ko seni to tii le so nnkan ti Adunola le se lori oro atawon ileri to n le naa.

Okan lara awon agba elesin Musulumi kan soro nipa oku,Ustaz Mhikail Shittu so pe bii pe won n fiya je oku ni ki won maa je ki oku pe nile, atipe bawon eeyan, paapaa awon ebi ba se n ri oku naa ni won maa maa banuje, ti okan won maa maa gbogbe.

Ase ni won lawon ebi baba oloogbe naa, iyen Victor Olaiya ti won ni se lo ti ara mo inu ile lori ironu iku omo e to soju emi e. won ni egberun meedogun dola ($15,000) ni won maa gba lati fi sin oku nilu Canada, atipe idaji owo naa ni won maa fig be oku pada si Naijiria.

Idi toro naa fi ri bee ni pe, ko tii to odun meta ti Moji Olaiya wonu esin Islam lati inu esin Kirisiteni to n se tele, inu esin Islam lo si ku si.

Opo awon ololufe to gbo iroyin nipa iku Moji lo ti n lo sile e to wa ni Magodo nilu Eko lati lo ki mama e atawon ebi e ku ara feraku, ti onikaluku won si n soro nipa oloogbe naa.

Lara awon to lo kii ni Doris Simeon; Ronke Ojo, Oshodi Oke; Bisi Ibidapo Obe; Ronke Odusanya.

Agba osere nni, Yinka Quadri naa foro ibanikedun ranse, o so pe ohun ko le so nnkan to n sele lori iku awon gbajumo osere tawon feran, o ni Moji Olaiya je enikan to nife awon eeyan pupo, o si mo ise e nise.

Bee naa ni Yomi Fash-Lanso naa so pe iku obinrin naa dun awon pupo nitori pe ironu iku Pasito Ajidara lo si wa lara awon. Bakan naa ni funke Adesiyan so pe ibanuje nla niku oloogbe naa je foun nitori awon nnkan to ti se foun ni daadaa.
Bi nnkan ba tun se n lo si, ni AWIKONKO yoo maa mu wa fun un yin lati ka.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI