Labake ri owo he, lo ba gbee lo banki ni Sagamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 19, 2017

Labake ri owo he, lo ba gbee lo banki ni Sagamu

Labake pelu aso FCMB lorun
Opo awon alaimokan to gbo oro odomobinrin eni odunmokandinlogun, Samson Labake ti ile eko girama Muslim High School to wa lagbegbe Sabo nilu Sagamu nipa poosi to ri he, to si mu lo si banki, iyen FCMB lojo Isegun Tusde to koja yi ni won n so pe omugo ni, ko ye ko se bee.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni osan ojo naa leyin ti Labake to wa ni ipele karun (SS2, Art) kuro nileewe lati maa lo sile, lo ri poosi naa loju ona, nigba to si ye e wo, owo to to egberun mejidinlogun lo ba ninu e, iyalenu lo je fun un, aanu eni to ni poosi naa si se, ko si mo bo se le wa eni to ni poosi naa ri.

Eyi lo je ko tubo tu poosi naa, to si ri kaadi ti won fi n gbowo, iyen ATM eni to nii, loju ese lodominrin Labake gba banki to wa lara ATM naa lo lati so fun won pe oun ri poosi naa he, atipe ATM toun ri ninu e lo je koun woo pe o seese kawon osise banki naa mo eni to nii.

Lakoko ti won fi han fawon ekegbe e
Bawon osise banki se gbo nkan ti Labake so yi, se ni won so pe gbogbo won lanu sile paapaa awon eeyan to wa si banki lojo naa, bo tile je pe se lawon kan ni omo naa ponu, se lo ye ko yo owo, ko si ju poosi naa sile.

AWIKONKO gbo pe lesekese ti eni to je gege bi alakoso banki naa ti gba oruko Labake sile, to si seleri pe oun yoo yoju si nileewe lojo keji lati daa lola. Sugbon nigba tawon toro naa soju won maa gbe oro naa, se ni won n so pe egberun lona igba naira ni owo to wa ninu poosi ti Labake da pada.

Gbogbo bawon eeyan se n gbo, ni won n fi tiwon kun un, ti won si n so pe egberun lona eedegbeta, ati beebeelo lo wa ninu poosi naa, opo awon eeyan naa tun n sepe pe lorisirisi.

Ko seni ti ko gboro Labake nilu Sagamu lojo naa, bo tile je pe orisirisi oro aheso lo n jade lati enu awon to n gbe iroyin naa kaakiri. Lojoru Wesde lakoko tawon omo ileeko naa ti wa ninu kilaasi won la gbo pe awon osise banki naa de sile eko girama tawon Musulumi naa, ti won si gba ofiisi oga agba, Ogbeni Oyenuga Davies lo lati lo salaye.

Labake ati Iya e, Abosede
Bi Ogbeni Oyenuga se gbo, lo ti so fawon osise wipe ki won lo pe gbogbo won jade sita lati wa gbo tuntun, won si mu Labake jade sita fun won nigba ti won n so nnkan to sele.

Sugbon ko too di akoko yi ni Oyenuga ti ranse si iya Labake, Arabinrin Abosede Samson pe ko wa, awon osise banki fee ri, won si fee da omo e lola, inu obinrin naa dun, o si gba ile eko Labake lo.
 
Okan lara awon osise banki FCMB, Ogbeni Adefolurin to wa nibe lojo naa seleri wipe awon yoo fi oro naa to awon oga agba patapata ni Banki won leti, ti awon yoo si fi ebun to joju ta Labake lore fun ti iwa omoluabi to hu.

AWINKONKO tun rii gbo pe loju ese lawon ore Labake ti bere sii jowu, nigba ti won si se tan ni won bere sii ki ku oriire, awon kan ti e so pe se lawon banki naa fee fun ni eto eko ofe lati fi daa lola.

Labake ati Arabinrin Isikalu
Nigba to n gba enu oga ogba ile eko girama naa soro, Arabinrin Isikalu so pe iwa ti Labake Samson hu lojo naa je eyi to yani lenu pupo, ati pe iru iwa to ye omoluabi lo hu nipa gbigbe owo naa lo si banki.

Isikalu sapejuwe Labake gege bi omo ti kii ja nileewe to si ja fafa lenu eko e, o wa lo akoko naa lati gbawon akeko kaakiri orileede yi lamoran pe ki won fi ti Labake se arikogbon nitori pe iwa rere leso omo eniyan. O loun mo pe ibi giga ni Labake n lo.

Bakanna lo fi kun oro e pe awon osise banki naa ti so pe awon yoo tun pada wa lati wa so esi tawon alase ba fi fun awon lati le je ki araye gbo.

Iya Labake, Arabinrin Abosede nigba to n ba AWIKONKO soro ni aago meji geerege osan oni, o so pe inu oun dun fun iwa ti omo oun Labake hu nitori pe nnkan toun nigbagbo ninu e nipe nnkan teeyan ko ba sise fun kii pe lowo eni, lara awon eko toun si n ko awon omo oun niyen.

Iya Labake, Labake ati Tisa e, Arabinrin Ajilore
O ni aheso tawon eeyan n gbe kaakiri ni pe egberun lona igba lowo ti Labake gbe lo si banki, ti won si n sepe lorisirisi, sugbon oun nigbagbo wipe epe won ko le ja omo oun, ayafi to ba je pe iwa to hu naa je iwa ti ko bojumu lawujo.

Labake ninu aso ileewe e
O so pe looto lawon ko yo, sugbon ebi ko pa awon nitori o ti to odun merin ti baba Labake ti ku, to si je pe oun nikan loun n da gbo bukata awon omo oun, atipe Labake ni akobi omo oun.

Bakanna lo tun wa fi kun oro e pe awon osise banki naa ti so pe koun ati Labake yoju lojo Aje Monde lati wa gbo esi abajade ipade tawon ba se pelu awon alase patapata nileese banki awon.

AWIKONKO ko nii da iroyin yi duro sibi, nitori eti to ba gbo alo, gbodo gbo abo e. Eku oju lona.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI