Ayeye odun ilu ile Afrika; Ipinle Ogun gbalejo kaakiri agbaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 9, 2017

Ayeye odun ilu ile Afrika; Ipinle Ogun gbalejo kaakiri agbaye

Ojo malegbagbe lojo ti ipinle Ogun sayeye odun ilu ile Afrika nitori pe titi di oni lawon eeyan si n kan saara sijoba ipinle Ogun lori eto ayeye odun ilu olodoodun ti won pe ni African Drum Festival ti won se lose to koja, eyi to bere lati ojo Eti Fraide ti won si se asekagba e lojo Abameta Satide osu to koja.

Bo tile je pe ko seni to lero pe ayeye naa yoo dun ju todun to koja lo sugbon nigba tawon eeyan kaakiri ile Afrika paapaa lati orileede Amerika bere sii bole lati inu oko baluu nilu Eko to si je pe ilu Abeokuta ni won n lo lawon eeyan ti bere sii mo pe ijoba ipinle Ogun ko mu oro naa ni kekere rara.

Sugbon lojo Eti Fraide ti ayeye naa bere ni nnkan bi aago marun ti eto naa bere loni pereu, ko seni to wa ni gbagede Asa, iyen Cultural Center to wa ni Kuto Abeokuta tie to naa ti waye lojo naa to fee ki eto naa pari lasiko nitori bawon to wa fi ilu ori ati ijo dawon laraya.


Lojo naa ni Ooni Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi; Oba Lamidi Adeyemi, Alaafin Oyo; Olu Ilaro ati Oba Alaye ile Yewa, Oba Olugbenla; Alake tile Egba, Oba Adedotun Aremu Gbadebo; Olowu tilu Owu, Oba Adegboyega Dosumu, to fi mo Gomina ipinle Bayelsa, Seriake Dickson wa nikale lati ye ijoba ipinle Ogun si.

Nigba to n soro, Oba Lamidi Adeyemi so pe inu oun dun lati wa nibi ayeye odun ilu naa nitori pe iru e ko sele ri lorileede Naijiria, akoko re e. O ni bo tile je pe oun ko raaye lati wa lodun to koja lati mo bi ayeye naa se lo si nitori pe ilu Maiduguri loun wa, sugbon oun ko kabamo pe oun wa nibi ayeye todun yi.

Alaafin tesiwaju pe ilu kii se ohun elo yepere nile Yoruba nitori pe ohun gan lo je Pataki ti a fi n ba ara eni soro, paapaa laafin. O ni bi won ba fee ki eeyan nilo paapaa awon oba, bi won ba fee gba eeyan lamoran, ko si nkan meji to dara lati lo bi ko se ilu. O ni nigba ti won ba fee ji oun loju oorun, ilu ni won fi n pe oun, a o si gbodo je ko parun.

Bakanna lo so pe ninu gbogbo ilu to wa kaakiri agbaye, ilu tile Yoruba nikan lo le soro, ko tun si ilu miran to n soro. O wa lo anfaani naa lati fi gbawon omo Yoruba, paapaa awon omo Afrika lamoran pe ki won ma se gbagbe asa ati ise won, ki won si maa ri daju pe won n gbe e laruge nibi gbogbo ti won ba n lo.

Ooni naa soro ile kun, o ni gbigbe asa ati ise ile wa laruge nikan lo le je ki a mo pataki awon nnkan meremere ti a ni nile Yoruba. O so pe inu oun dun lati wa nibi ayeye naa.

Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ninu oro ti e dupe lowo awon to fi orileede won sile lati wa kopa nibi ayeye odun ilu ile Afrika todun yii. O ni todun to m bo yoo larinrin ju eleyi lo.

Lara awon orileede to kopa la ti ri orileede Ghana, Haitti, Togo,
Congo, Burkina Faso, Benin atawon min in. Bakanna ni ipinle Eko, Edo, Ondo, Benue, Niger, Oyo, Osun, Anambra, Borno ko gbeyin nibe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI