Emi o se oselu eleyameya o – Paseda - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 16, 2017

Emi o se oselu eleyameya o – Paseda

Ninu oloselu lorileede Naijiria, nitori pe laarin osu mefa to de lati wa dupo gomina nipinle Ogun lodun 2015, ipo kerin lo se nigba naa to si mu ki opo awon eeyan maa kan saara si wipe ise lo se. Ajosepo e laarin awon oloselu to ku lorileede yi ko see fenuso tan nitori pe gbogbo egbe oselu patapata lo n ba se, ti won o si soro laida. Lojo ti Otunba Rotimi Paseda ba AWIKONKO soro laipe yi nile to wa nilu Eko, o soro ile kun. E kaa awon oro to ba AWIKONKO so, paapaa nipa oselu eleyameya to n pa wa ku lo lorileede Naijiria.

Paseda
AWIKONKO: Oruko yin?
PASEDA: Oruko mi ni Otunba Olatunde Ritimi Paseda.

Alaroye: Nje e le so fun wa nipa bi e se je, paapaa ipo yin lorile ede yii?
Paseda: Emi ni asiwaju egbe oselu Unity Party of Nigeria, UPN kaakiri orile ede yii. Mo gbe apoti idibo gegebi gomina ipinle Ogun lodun 2015 labe asia egbe oselu UPN.

AWIKONKO: Ti a ba ni ka wo, opo awon oloselu lo ti kogba wole paapaa awon oludije ti e jo gbegba apoti idibo lodun 2015, eyin nikan lo je pe e si wa nita lowolowo, se kii se pe ti imurasile idibo odun 2019 lo faa ti e si fi wa nita di akoko yii?
PASEDA: Bakan meji ni. Akoko ni pe gbogbo nnkan to je mo anfaani fawon eeyan lo je mi logun, lati maa wo awon nnkan to n sele laarin ilu ati awon nnkan to n sele nipa nnkan ti ijoba nse. Oro awon eeyan je mi logun paapaa awon araalu mi atawon osise ijoba. Eleekeji ni pe, gbogbo wa la mo pe ibere kii se onise a feni to ba foriti de opin. O di dandan nigba ti a ti se leekinni ti a gbegba oroke, 2019 tun nbo, ti a si ni eto ti a fee se, o di dandan ki a duro lati bere si nii gbe igbese lori bi o se maa seese fun wa lodun 2019.

AWIKONKO: Nje esi eto idibo to koja lo ko mu ifaseyin ba yin paapaa awon omo egbe oselu yin?
PASEDA: Ko si ifaseyin tabi ikunsinu kankan, won ni owo tomo kekere ba koko pa, akara lo maa fi je. Nnkan ti agbalagba n ri lori ijokoo, tomode ba gun akaba, won ni ko le ri. Idibo 2015, emi gege bi enikan mo wipe, a se daada, sugbon osu mefa la ni lati fi gbaradi fun idibo tawon mi in fi odun merin gbaradi fun. Ninu osu mefa naa, a gbiyanju nnkan taa le se lati ko awon eeyan jo. Sugbon o seni laanu pe kii se gbogbo ibo to je ti wa ni won ka fun wa. Ti a ba ni ninu gbogbo egbe oselu to wa nipinle Ogun, ti egbe to jade laarin osu mefa si se ipo kerin laarin won, mo ro pe o ye ka gboriyin fun iru egbe oselu bee pe o gbiyanju nitori pe awon kan wa ti won ti ja seyin tipe. Ko si ifaseyin kankan nitori pe a mo nnkan ti a fee se. Mo mo pe ki eni to ri je ko fun eni ti ko ri je, ohun gan gan lo se pataki. Emi wa lati wa pa ise da ni. Lati rii daju pe gbogbo awon nnkan to ku die kaato, to nje awon eeyan niya, ka wa iyanju si. Won ni ti iwaju ko ba see lo, ka pada seyin. Eyin yen gan-an ni mo fee pada si. A o le lo siwaju mo toripe won ti da gbogbo e ru, won ti baa je patapata, ka pada si nnkan ti a mo lati le fi tun iwaju se pada.

AWIKONKO: Ki ni ona eyin ti e so pe e mo ti e fee pada si?

PASEDA: O po lorisirisi. Akoko ni pe, ijoba lo wa fun awon araalu, kii se awon araalu lo wa fun ijoba. Ijoba ti a n wo lasiko yi lo je pe awon araalu wa fun ijoba ni, nitori pe ijoba lo maa pase fawon eeyan pe nnkan bayii loun fee, ko si nnkan to kan ijoba boya nnkan to fe yen te awon araalu lorun toripe ko kan won. Ijoba ti a mo ti a fee pada si lo je pe awon araalu lo maa so pe nnkan bayi lawon fe, ti ijoba si gbodo se e fun won. Gbogbo awon nnkan ti won maa n se nigba aye awon Baba Awolowo, bii Town Hall Meeting tawon oba maa n sagbateru e, nitori pe lati ayebaye, awon lo ni ase, awon oba lo n dari awon ijoba ibile, lo n se olori ilu nigbayen lohun. Bawo le se maa ni e fee se eto ilu, e fee se eto agbekale fawon araalu ti e o ni pe awon lobaloba si pe ki ni won ro nipa e. Opo ijoba ibile lo ni Town Hall, to je pe orule won ti si danu, tawon osise si wa nibe. Ise po lowo gomina, ko ye ki gomina maa tojubo awon nnkan to n sele nijoba ibile, ise ti e ni ko maa ba ijoba apapo dowo po, ijoba orile ede mi in dowo po lati mu awon ohun alumoni ti yoo pese ise fawon odo wole. Boya ijoba apapo fee ya wa lowo, ba wa sepade, ise ti gomina niyen. Ko si wa se abojuto si ijoba ibile lori owo ti ijoba apapo ba fun won, lati woo pe se nnkan ti won fi se niyen.

Otunba Paseda
AWIKONKO: Sugbon, ti a ba ni ka woo, opo awon oba lo je pe oloselu ni won, won ti mo ibi won nlo, won o si ni so ooto, nje irun nnkan bayii ko ni se akoba nipa oro Town Hall meeting yi?

PASEDA: Ko le se akoba rara. Otunba ni mi, oye Otunba temi kii se ti afe-aye, sugbon ti ibile. Omo Oba ni mi. Ko si nnkan to so pe mi o ni joba lojo kan. Eni to ba mo agbekale ori ade, to tun mo eto ilu nigbayen, a a mo pe opo ninu awon yen loo n se ife inu won. Nigbati ijoba so pe oba o le jade lati ilu e si ilu ibomiran lai je pe o gba ase, oba o le fi eeyan joye lai je pe o gba ase lowo gomina. E ma je ka tan ara wa, Oba to mo pe toun ko ba ti fi ti gomina se, won a yo oun, o di dandan ko se oselu, Iberu ni. Nigba ti a ba gbe awon ilana naa pada si bi o ti wa tele, ee ri pe awon oba gan a se nnkan to ye ki won se. Awon oba kan si wa to je pe won a so fun ijoba pe ko si nnkan to kan awon, nnkan to ba wun awon lawon maa se. Won a so pe kii se owo, tabi ipo loun gbokanle, ki gomina too de loun ti njoba, ko si lase lati yoo kuro. Awon oba kan wa bee. Ti a ba da ase pada sibi to ye ko wa, ti a fi awon oba se asiwaju, kii se a o ni ni alaga ijoba ibile, sugbon awon to je ti ibile, to je awon ni won mo ayinike ati ayinipada bi gbogbo nnkan se n lo, ti a fun won ni aaye ati oore ofe, won a se nnkan to ye ki won se. Gomina a wa fun odun merin, o n lo, alaga ijoba ibile naa a wa fodun merin, sugbon oba wa titi, ko nibi to n lo, a fi to ba papoda. Kii se idunu awon oba ni lati maa se ibaje, to ba je bee ni, ko soba to maa se nkan tawon araalu nfe.

AWIKONKO: Opo awon oloselu lo ti n so pe egbe oselu to gbooro, iyen mega party lo se eto ilu daadaa, ki le ri si?
PASEDA: O le sise, a mo sa, 'sugbon' wa n be. Ti olosa mewaa ba ko ara won jo lati da egbe kan sile, ole naa ni won si maa ja, e ma je ka tan ara wa. Nigba ti awon alaanu eniyan ba ko ara won jo, ko sogbon awon naa a je nibe nitori ibi ti a ti n se ni a ti nje. Sugbon ti eeyan ba fi aanu sowo, ere po nibe, nigbati iru awon eeyan bee ba ko awon jo, o di dandan ko seese. Nigba temi koko bere, mo je ko ye won pe emi o se oselu eleyameya, eni to ba fe ni ko tele mi, eni ti ko ba fe, ko pada leyin mi. Ko seni ti mi o le ba se. To ba ti je awon oloselu to se daada ni won fee gbe egbe nla po, mo setan lati bawon se. A fi ka sora lati ma se ko awon eni buruku mo awon eniire. Awon egbe kan wa to je pe won bere ni daada, afigba tawon kan wole ko to di pe tara won ni won mo. Osise ko ba ma rowo osu gba, awon eeyan o ba maa ku lojoojumo, ko si nnkan to kan won. Won o fi annu se ijoba. Awon orile ede toku ti a n wo, aanu ni won fi n se ijoba ti won. Ki won to gbe igbese kan, won a wo ti mekunu. Awon oloselu won a ri je, araalu naa a ri je, eeyan le ma le je obokun, sugbon, a je eja.

AWIKONKO: Kini ojuwoye yin nipa ayipada ti ijoba to wa lode bayi n pariwo nipa ara to n ni awon araalu. Se o digba tawon araalu ba bere sinii fehunu ita gbangba han. Ki ni ero pe o le je atunse?
PASEDA: Amokun reru, a ni o wo lori, e o wo isale. Ti a ba fee so tooto, gbogbo nnkan ti a ba ara wa ninu e yi, ti a n jiya e yi, kii se ejo Buhari. Igba wo lo de be? Nnkan ti baje tipetipe, lateyin wa, to si tun n baje si. Won ni ko bi a se le tun nkan se ti ko ni ni awon eeyan kan lara. Tibi tire la da ile aye. Ko si bi a se fe se nnkan ni daada, ti awon kan ko ni fara gba iya e. A n jiya ki a le jere ni. Ko si bi Buhari se le se atunse yi laarin osu kan, odun kan paapaa, ko seese. Sugbon awon igbese ti Buhari n gbe yen, igbese to dara ni, o si nira. Laipe yi ni won sope won fun NNPC ni aaye to po nibi epo, awon kan so pe ojusaaju, sugbon kii se bee. Ojusaaju yen, irorun fun awon mekunu ni nitori NNPC ko le ta epo koja 86naira ni lita kan. Awon ile epo kan wa ti won nnta epo ni 180, 200 losan gan gan. Ti epo ba po ni NNPC, ero maa dinku lawon ile epo aladani to n ta ni owo goboyi. Nnkan ti mo ri ninu awon igbese Buhari ti mo ri pe o ku die kaato ni pe, oo le diju koo da omi too fi we fomo, basia too fi we fomo atomo danu. Ipele lo ye ki Buhari se gbogbo awon igbese to n gbe yen. Akoko, o ni o fee so oro epo di irorun fun mekunu, o gbodo koko fun mekunu ni akiyesi nnkan to mAa sele lola sile lonii. O ye ko ti so pe bi apeere, iresi, ojo bayii ni ko fi ni wole mo nitori naa ati si boda sile, kawon eeyan ti wa ni imurasile, won a ti maa ko ounje wole ki irorun le deba won. Sugbon Buhari ko se bee. Awon to so pe oun n tori e se nnkan wonyii lo n jiya lowo bayii. Awon to fee yo kuro nidi jegudujera yii, to ba pe baagi iresi kan ni egberun kan dola, won a ra, won a je, won a tun da ninu e nu nitori pe owo wa, sugbon se awon mekunu le ra? Eyi ti mo le so pe o se to da ni pe, won ti bere sii fo epo lorile ede yii, ko si ijoba to dan wo to rii se, tori awon ti ko ni je ko seese po ju awon to fe ko seese lo. O tun fun awon onileese adani laaye ti won le se ileese ti won ti n fo epo loni kereje, lati wa gba iwe ase. To ba ya, epo maa po debi pe gbogbo wa maa gbagbe iya ti a ti je seyin. Ani lati ni suuru nitori won ti ba orile ede yi je lati odun to po seyin.

AWIKONKO: Nje e ro pe awon iri ajo Buhari sawon orile ede kaakiri le so eso rere kan?
PASEDA: Ti ko ba rin awon irin ajo yi, a o le de ibi kankan lorile ede, oju kan soso la maa wa. Wipe Buhari nna owo lati rin irin ajo, o di dandan ki eni to ba fee jade wo moto, paapaa olori oko, o ni lati ko awon eso e dani. Eekeji, se eni teeyan fe baa da owo po, ko ni lo baa sepade po ni? Se ti a ba n wa nnkan lodo enikan, se ka jokoo sile pe ki won waa ba wa ni? Ko seese, a fi ko lo ba won. Fun idagbasoke orile ede Naijiria ni, ati lati dekun iwa ajebanu lawon igbese to n gbe. Eni to ba n wa nnkan lo ye ko maa sare kiri. Awon owo ilu ti awon oloselu ti ko lo soke-okun, gbogbo awon ibi ti won kowo pamo si, ona bo se maa ri awon owo naa gba pada lo n wa nipase awon irin to n rin. Ko tii gbe nnkan to fee se jade ni, won ti mo awon to ti je orile ede yi run, won o ti fee maa daruko won ni. Awon ilu ti won nkowo wa pamo si ni won nlo yen. Ni orile ede agbaye, orile ede Amerika lo lagbara ju, Russia tele, sugbon ida idamokandinlogorun awon omo orile ede Amerika ati Russia lo n gbe orile ede China kaakiri. Opo nnkan ta n lo lagbaye paapaa lorile ede yii lo je pe China lo ti n jade. China je orile ede to tobi ju nipa idagbasoke ileese teeyan le ronu nipa e. Ti n ba de ipo paapaa ipo gomina ipinle Ogun, emi naa a jade lati lo wa awon to le wa ba mi fa awon odo ilu lowo soke, nitori ni China ti a n so nipa e yii, awon odo lo n se ise owo yii ju, nidi ero alagbeka, awon odo le maa ba nibe. Eni to ba n wa nnkan lo n sare kii se eni ti won n lo ba fun nnkan. Ti won ba so pe ki won ko awon orile ede ti Olorun feran ju, ninu meta, orile ede Naijiria wa ninu won. Somalia ko to ida meta orile ede wa ti won ri isoro kekere lasan ko to di pe won fon ka, titi di oni, won o ti yanju oro won. Ilu to n na iju iye to n ri gba lo, ilu naa maa fo gbeyin ni, sugbon orile ede yi ko ri bee nitoripe Olorun feran wa. Owo ti a nna ti poju, ojoojumo ni a n je gbese. Epo ti a si fi nnduro, to ba ya, epo wa o ni to nnkankan mo. O ye ki oju ti wa nitori pe isana to kereju lo, orile ede China ni won ti n ko wole, gbogbo nnkan ti a le fi se isana lo wa lorile ede yii.

AWIKONKO: Leyin ayeye ogoji odun ipinle Ogun lo ti je pe won ti pa awon akanse ise ti won so pe won n se ti, se ijoba la ni nipinle Ogun yi abi ki le fee so si?
PASEDA: Oro ipinle Ogun, se lo dabi bi onigba ba se pe igba e. Igba se bo se wun e ni oro ipinle Ogun, igba gbese lo maa je ku, igba ma fun araalu je, nnkan to pe igba e ni won baa gba. Awa la so pe nnkan to wun wa niyen, toripe won o fi tipa tipa mu wa. Eni to ba je olori oko, ti awon to ba yii ka ba je eeyan buruku, ko si bo se le wu ko ri, o maa sina saa ni. Toripe bi Olorun se da wa, ko seni ti won maa gbe gun ori aleefa ti ko ni sise. Yala ki ipo yen gun tabi ki won sii lona, tabi ko jo ara e loju. Gbogbo awon to le too sona tabi pe si akiyesi, won o po. Awon to le so otito, ijoba ko je ki won duro toripe won o fe eni to maa gbo won lenu. Ni temi o, ijoba la n se nida kan, ijoba ko lan n se nida keji. Ijoba olowo la n se nipinle Ogun, kii se ijoba mekunu. A n se ijoba, sugbon gbogbo nnkan ti a n se naa, fun anfaani awon olowo ni. Gbogbo ogoji akanse ise ti won so pe won se, ki won wa so eyi to kan mekunu ninu e. Eyi to dabi pe o fi oju jo ti mekunu, mekunu gan an o le de be. To ba de be, ko si nnkan to fee fi se. Awon tori won pe repete ko po nijoba toripe ijoba ko fee awon ti won ko ni gboran sii lenu. Bi e ba de awon ile ti won ko naa, ko si nkankan nibe, bee naa lawon ileewosan ti ko wulo ti won ko toripe ko si noosi ati dokita ti won yoo sise nibe. Eyi tawon osise wa, ko si irinse fun won. Gbogbo nnkan ti won maa fi toju awon eeyan ni won maa ko fun won pe ki won lo ra, ki lo de tijoba ko le pese awon nnkan won yii? A n se afara oloke, mi o ni ka ma se, awon afara oloke kan wa ti ko wulo toripe latigba ti won ti se, ijamba oko dinku lagbegbe naa. Idi niyii ti mo fi so pe ka pada seyin lati tun awon nnkan to. To ba je ki won to bere awon ise wonyii ni won ti se ipade Town Hall ni, awon araalu a ti pariwo sita awon ko fe biriji sawon agbegbe kan ti ko ti wulo. Won a ti pariwo pe ki won se titi nikan, ki won se omi to ja geere fawon. Nigba aye awon Baba Awolowo, won se kini omi igbalode to si di akoko yi bo tile je pe ko sise mo. Leyin tigba Baba Awolowo, ko tii si ijoba to tun ko mi in nipinle Ogun. Ki lo fee na ijoba lati fi owo se omi fawon araalu. Igba kan la n si omi ninu ile, sugbon bayii, ko si opa to gbe omi wole mo, ka ma sese so pe ka si omi. Gbogbo nnkan ti won le fi se omi yi lo wa nle, ki won tun un se nikan ni. Ijoba kan n fi ojoojumo ya owo ni, dandan ni ki eni to je gbese san an, sugbon ki la fee fi san? Ti won ba gbaa sotun sosi, ti won o ba ri bi won se maa san gbese ti won je, owo ori araalu ni won maa yi mo. Ta lo fee san owo ori? Ijoba o ya awon kan soto lati maa san owo ori, bi apeere awon to n gerun. Ti agerun kan ba gerun igba naira mewa lojumo, ti won ni ko wa san owo ori egberun meji, ninu owo to n pa lo ti maa yo owo ile, owo epo generato, lo ti maa tun awon irinse e se ati beebeelo. Gbogbo eeyan nijoba fee maa gba owo ori lowo won paapaa awon ti ko sise. Won o le so bee toripe gbese ti won je, won ni lati san an pada. Ibi ti won n lo bayi ni pe, ti eeyan ko ba mu kaadi pe o san owo ori dani, ko ni le rin loju titi. Ipinle Eko se, ti eeyan ba paaki moto segbe titi, a fi ko san owo, ti won ba gbe moto lo, ki won to ba eni naa soro, won a ni ko lo mu iwe to fi san owo ori wa, iru eni bee a wa sese maa sare kiri lati san owo ori tori ko le ri moto e gba pada. Ijoba to ba gba ipo lowo ijoba to wa lode yi, to ba ro pe oun le ri ole kan ja, aa ya lenu pe gbese lo maa ba nile, sugbon sibe aa si fee jale naa toripe ironu wa ko ju ka jale lo. Ijoba to ba si teri si gbese naa, aa te lowo araalu. Nnkan ti Buhari si n dojuko niyen to fi di pe o n te lowo araalu. Opo araalu lo si ti n so pe ki won je ka pada si iwa ajebanu to ba je pe iya ti a fee je niyii. Kii se ejo e, o teri si nnkan to gba lowo Jonathan ni. Ko si ipo ti o soro lati se, sugbon ipinu lati se daada lo maa je keeyan le se aseyori.

AWIKONKO: Nje e ro pe a le ya bara kuro lori oro epo lasiko yii, nje o le seese lati so pe a fee sare ya bara?
PASEDA: Ki lo de ti o le seese? O seese. Ti o ba si seese, o ni lati seese ni. Won ni ti a o ba mo ibi ti a n lo, aa pada seyin. Epo ko ni won fi da Western region sile, koko, ise agbe ni won fi daa sile to si mu idagbasoke ba. Nnkan to kan wa nibe ni pe ise agbe kii se nnkan to le bere lonii, ko si ko ere e lola gege bii koko. A ni lati mo nnkan to wa laarin ka gbin ati ki a ka. A gbodo ronu siwaju pe bayii la se fee se. A le duro lori nnkan ogbin nikan lorile ede Naijiria, o seese. Sasa ni orile ede to ni iru afefe ati ile ti Olorun fun wa lorile ede yii. Ti a ba lo sorile mi in bii Pakistan, ti e ba n rin irin ajo fun bii wakati meji, egbe otun ati osi, nnkan ogbin nikan le maa maa ri. Sugbon lodo ti wa n bi, igbo lasan le maa ri. Ko sigba taa ni kuro lori oro epo tori pe awon oyinbo ti se awon moto ti kii lo epo mo, to je batiri ni won n lo.

AWIKONKO: Nipa oro owo ti oni bilionu mejo dola ti orile Naijiria ati China towo bowe adehun e, to je pe Dangote nikan gba ida merin ninu e, nje ko le ko wa si oko gbese ojo iwaju?
PASEDA: Ibeere to ye ki gbogbo wa koko beere ni pe kini Dangote fee fi owo naa se? Atipe ki ni ere ijoba lori nnkan to fee se?. E ma gbagbe pe owo ti won nna lati fi gbe epo wa lo si ibi ti won ti n fo ti won tun maa da pada wa fun wa nibi lati lo, o to ilopo meta. Owo to je pe ti a ba se ninu ilu wa, owo naa a lo sile, epo a po repete. Dangote pelu awon ti won ni ileese ti won ti n fo epo. Won o le deede fun Dangote nikan lowo laini idi pataki. O le ma je Dangote lo maa gba owo naa ko je pe ileese miran ni, sugbon oun lo mo ona ti a le gba lati je ki epo po to si maa se ilu lanfaani. Ajosepo ni Dangote ato orile ede yii fee se. Ti ki baa se ko le daa ni, won o le fun Dangote lowo ko lo fi ko le tabi fi se nnkan miin. Sugbon nnkan to fee fi se lo se koko, iyen lo sokunkun si araalu. To ba je araalu mo ni, won le ma soro. Aare ti a ni yi ni won n pe ni oba talaka. Ni ilu e, asiwaju awon talaka ni. Ko fi oro talaka sere rara.

AWIKONKO: Bawo ni oro egbe oselu yin, UPN?
PASEDA: UPN tawon eeyan mo nigbayen ti di repete, o ti gbooro sii. Opolopo awon ti won kuro ninu egbe PDP ati APC nipinle Ogun ni won ti darapo mo egbe UPN. Mo ni lati maa so fun won pe egbe UPN ti mo je asiwaju e lorile ede yii, emi o se eleyameya. Eni to ba wa, to ri bi a se n se, ti ko ba tee lorun, a a pada fi wa sile ni. A o ya enikankan soto. A fe awon ti won le tun ilu wa se ki won wa gba ipo. Ti a ba ri eni to le se asiwaju ju mi lo, mo setan lati lo jokoo, lati maa ba iru eni bee damoran. Kii se dandan. Ohun taa ba se lonii, itan ni lola. Itan yen, ati oruko rere yen lemi n wa. Itan bi itan Baba Awolowo tawon eeyan si ma maa so leyin ogorun odun ni mo n wa. Eni to ba mo pe oun le se ni daadaa la n wa ninu egbe UPN. Nipa adari UPN, Baba Faseun, agbalagba niwon, asiwaju si ni won pelu. Oludamoran ni won je nipa pe bi a ba fee sina, ki won pe wa si akiyesi lati to wa sona. Agba lo n ri nnkan tomode o ri. Won o si nidi oselu mo rara gege bii nnkan ti a gbo. Awon agba ti a ni bayii lawon agba nidi oselu, iyen awon ti won ba Baba Awolowo jokoo se oselu, merin ninu won la ti ni bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI