Isokan FIBAN lo jemi logun – MC Murphy - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 17, 2017

Isokan FIBAN lo jemi logun – MC Murphy

MC Murphy
Ogbontarigi to tun je agba sorosoro lorileede Naijiria, Alaaji Moruph Sorunke, topo mo si MC Murphy ti so pe isokan ati itesiwaju egbe Freelance and Independent Broadcasters’ Association of Nigeria, FIBAN loun n wa, nitori pe nnkan to je oun logun ju niyen.

MC Murphy soro yi lana ojo Isegun Tusde nilleese Murphy’s Place to wa lagbegbe Ita-Oshin nilu Abeokuta nibi ayeye kan to waye ni rampe, nibe lo ti so pe gbogbo irin toun n rin ati awon igbese toun n gbe, ki egbe naa le nilosiwaju ni.

O ni oun kii fi be lo si pati to ba ti je okan lara awon sorosoro lo n se MC nibe nitori pe won ko ni gbajumo nnkan ti won n se mo, oun ni won maa maa ki ni mesan me wa lai kii se pe oun loun pe won wa sibe.

Kasnaty, Omo-Baba-Tisa ati Atunbi
O so pe oun ti dagba koja koun atawon to ba oun nidi ise naa jo maa du ise gba, iyen pe ki won jo maa du MC gba lowo awon to ba fee sayeye. O ni oriire awon to m bo leyin loun n wa nitori pe idunnu oun ni kawon to n ri oun gege bi agbalagba maa se rere loju emi oun.

MC Murphy so pe ireje loun ko, oun ko le gba ki enikeni fi iwosi lo oun nitori e loun se ki fun ijoba ipinle Ogun lodun ti won fun Gbenga Adeyinka lowo kan, ti won si foun ni owo ti ko to idaji ti e, o ni Gomina lo sese wa fi kun owo naa foun.

O wa gboriyin fun alaga egbe FIBAN fun awon ipa to ti ko gege bi alaga ninu egbe. O ni ko tii si alaga bii ti Alawiye lati toun ti n ba alaga pade, ipa to si ti ko, ipa rere, atipe awon olote tabi awon eeyan keeyan lo maa so pe ki ni Alawiye.

Olori, Murphy, Osila, akekoo Mapoly
O so pe ko seni toun feran ju ninu egbe FIBAN bi ko se Alawiye, idi si ni pe oun nikan lo maa n foun ni owo (respect) to si oun, to si je koun sagbateru eto idibo to wole, to mu oun maa dobale kaakiri. O ni Alawiye lo so foun pe koun lo gba ipo Akowe Akapo (Financial Secretary) apapo egbe naa, bo tile je pe oun ko fi bee mo nipa oro oye tabi ipo, eyi ti ko je koun kaa si.

Kii se aheso tabi oro enu lasan wipe Alawiye lo koko gbe ogbon kalenda wa sinu egbe FIBAN, ti ko seni to ronu e latodun ti won ti da egbe naa sile lorileede Naijiria. Okunrin naa lo si koko so opolo kale pe ki won maa fun awon agbaagba sorosoro lami eye (Award).

Ise, ipa ati ilana ti Ogbeni Akinyemi Alatoye, Alawiye fee fi sile gege bi alaga FIBAN kii se eyi to see gbagbe titi lai ninu egbe naa lorileede yi.

Osila ati Alawiye
Nigba toun naa n soro, Alawiye so pe oun dupe lowo MC Murphy nitori pe agba ti ko se e foju pare ni paapaa ninu egbe FIBAN, o wa lo akoko naa lati tun fi dupe lowo awon omo egbe pelu ifowosowopo ti won ni pelu oun nigba toun je alaga.

Olojo ibi ojo naa, Omo Baba Tisa nigba toun naa dupe lowo awon ololufee to wa sibi ojo ibi naa nitori pe bi kii ba se ife ti won ni soun, oun ko ni ri enikeni. Bakanna lo so pe ko si ninu eje oun lati maa sayeye ojo ibi, sugbon iyawo oun lo pon ni dandan foun pe a fi koun maa se e.
Eniola Sodiya, Elekeru ati Kasnaty

O so pe lodun to koja loun le so pe ayeye ojo ibi oun bere nitori pe iyawo oun lo se keeki toun ko mo, sugbon pelu gbogbo wahala tawon se lojo naa, oun ko ranti je keeki naa, pelu ija loun fi je keeki leyin ojo keta.

Bee lo tun dupe lowo MC Murphy lori awon ipa to n ko nigbesi aye oun nitori pe oun leni to maa koko mu oun wo ileese radio OGBC nigba toun fee bere sii soro lori afefe.

Siwaju asiko yi Yeyeluwa Ibiyemi Ajadi naa ti koko soro pe eeyan daadaa ni Omo Baba Tisa nitori pe oun ko le awon ibi tokunrin naa ti ran oun lowo.

Ore Oba mujo mukulu-muke
Oju awon eeyan ree
Lara awon to wa nibi ayeye ojo ibi naa ni Sunday Ogunsola,Tantala; Kolawole Adejojo, Kasnaty; Abass Adefulu, Atunbi; Shina Amodu, Agba Oro; Abiodun Sorunke, Owu Alantakun; Oloburo; Elekeru, Aderoju Ogundiran, Osila; Okanlomo; Rasheed Ojelabi; Perspe; Olori atawon mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI