Ibanuje nla lojo ti won sinku Pasito Ajidara je - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 30, 2017

Ibanuje nla lojo ti won sinku Pasito Ajidara je


Oku Pasito Ajidara ki won to sin in
Ko seni to wa nibi ti won ti sinku agba osere tiata nni, eni to tun je Gomina fegbe Theatre Arts and Motion Pictures Association of Nigeria, TAMPAN nipinle Ogun, Oloogbe Samuel Adesina Adesanya topo mo si Pasito Ajidara, ti aanu ko ni se nitori bawon ebi e atawon osere tiata to wa nibe se n gbera sanle pe ki won mai tii sin in.

Lojo Eti Fraide ose to koja yi ti won sin oloogbe Ajidara, ko too dipe won fi eeru fun eeru ati eepe fun eepe ni won ti koko gbe oloogbe naa yipo kaakiri ilu Abeokuta. Lati nnkan bi aago mejo aaro ojo lawon ololufe Oloogbe na ti gbera lati ogba awon osise NLC to wa ni Leme ti koko se eto ikeyin gege bi won se so pe okunrin naa je okan pataki ninu egbe awon osise ko too dipe o jade laye.

Ese ko gbero lojobo Tosde to koja yi ni gbagede Asa, Cultural Centre to wa ni Kuto nibi tegbe osere TAMPAN ti se ayeye ale ojo aisun awon osere lati fi se eye ikeyin fun oloogbe Ajidara. Nibi tawon olorin bii Ere Asalatu, Wole Papa, Chelsea Bobo ati Boye Best ti dalu bole mojumo.

Awon ebi Pasito Ajidara
Ka ma paro, ka si ma fi igba kan bo okan ninu, nnkan tegbe osere TAMPAN se fun Gomina won to doloogbe fun ayeye ikeyin, o koja afenuso nitori pe gbogbo awon to wa nibi eto isinku lati ojo ti won bere, titi ti won fi pari e ni won n gbosuba kare fun won.

Lati ori Aare egbe naa, Omoba Dele Odule titi dori alaga igbimo eto isinku, Mista Latin, paapaa Yomi Fash Lanso ni won se nnkan tawon eeyan ko lero. Ko seni to fi oju kan oorun l’Ojobo Tosde si Fraide ti won se ayeye aisun ale awon osere ninu awon to wa nibe, nitori pe bi won se n sare sotun, ni won n sare sosi, lati te awon alejo lorun.

Lara awon to wa nibi ale aisun naa ni Madam Saje, Anter Laniyan, Ajoke Asewo, Remmy Shita Bay atawon min in, gbogbo won ni won se bebe. Awon eeyan to tun wa nibe ni Aare egbe Fiban, Desmond Nwachukwu; Akinyemi Olatoye, Alawiye; Sunday Ogunsola, Tantala; Olori Toyin Adeniji.

Lakoko ti won n se isin ikeyin fun oloogbe
Nibe ni Omoba Dele Odule ti bu enu ate lu iwa tawon eeyan n hu, paapaa lori ero ayelujara Social Media, o so pe nnkan to n dun oun ju ni ona tawon eeyan n gba lo Facebook paapaa ti nkan ba sele sawon gbajumo lawujo.

Dele Odule menuba awuyewuye to n lo laarin awon araalu nipa bawon osere se n ku lenu ojo meta yi, o ni kawon eeyan lo jokoo ara won nipa siso isokuso wipe awon osere to si maa ku si po.

O tenumo pe ojoojumo lawon eeyan n ku, sugbon ti osere tiata ba ku, oto ni nnkan ti aye maa ka si, paapaa bi iru eyi to sele yi. O ni kawon osere tiata lo fara won lele, ki won ma ko okan ara won soke nitori pe ojo ti a ba ti yan fonikaluku lati lo laye lo maa lo, ko seni to le ri iran eke senikeni.

Aare egbe TAMPAN so pe opo telo, awako, osise ijoba atawon onirru eeyan lo n ku lojumo, sugbon nitori pe awon eeyan ko mo won, won kii se osere tiata tabi gbajumo lo fa ki aye maa maa pokiki won. o ni isoro tawon osere tiata ni nipe won ko le se nkan asiri, nitori pe ko si nkan ti won fee se ti aye ko ni mo.  

Bakan naa ni Otunba Bolaji Amusan, Mista Latin so pe nigba toun koko ri aworan oku Moji Olaiya lori beedi ni osibitu to wa, o ni inu oun baje gidi gan nitori pe ko ye ki iru nkan bee sele rara. O ni ibanuje nla lo je fawon nigba tawon ba n ri orisirisi aheso iroyin nipa awon gbajumo lori ero ayelujara nitori pe sogun dogoji lawon ti won n gbe e kaakiri fi n se.

O wa gbawon araalu lamoran, paapaa awon odo wipe ki won ko eko to ye kooro nipa bi a se n lo ero ayelujara, nitori pe o je okan pataki to n fa ilosiwaju orileede yi pada seyin.

Nigba toun naa n gba enu awon igbimo egbe awon osise ileese eto idajo, iyen Judiciary Staff Union of Nigeria, JUSUN ti Pasito Ajidara ti figba kan je alaga won Ogbeni Tajudeen Edun, Olori Ebi so pe bi egbe TAMPAN se ko ipa to po lori eto isinku bee naa lawon egbe JUSUN naa ko ipa to joju nitori pe ko si ibi ti won ko ti kopa.

Ile egbe awon osise NLC to wa lagbegbe Leme, Abeokuta ni egbe JUSUN ti bere eto ayeye lojo Eti Fraide ti won si korin gbe oku e. O so pe eeyan tawon ko le gbagbe tawon yoo si maa topase ipa rere to fi lele ko too ku.


Awon nkan ti e o mo nipa Pasito Ajidara po repete
Pasito Ajidara gba awoodu ti won pe akori e ni asaaju to see fokantan (“As Most Dedicated Leader”) ninu osu to koja, iyen April.

Ogbon ojo ninu osu kinni ni Pasiti Ajidara gba awoodu ti osuba kare fun ti ifeyinti e, ti egbe JUSUN fun.

Egbe Preciuos Tone Artiste fun ni awoodu lojo keje osu keji odun 2016 to koja.

Flashlight Entertainment fun Pasito Ajidara ni awoodu irin ajo rere sinu egbe onigbagbo nilu Ijebu.

Awon odo ijo onisokan ti Kerubu ati Serafu fun ni awoodu fun ipa idagbasoke to ko ninu ijo naa lojo ketadinlogbon osu kokanla odun 2014.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI