Ileese
olopaa ipinle ti kilo fawon araalu pe ki won sora won loju ona Alamala nilu
Abeokuta latari ibon ti won lawon eso ologun to wa lagbegbe naa fee yin fun ojo
meji gbako.
Abimbola Oyeyemi |
Gege
bi AWIKONKO se gbo, kii se pe won fee mon-on-mo maa yinbon naa, bi ko se pe
awon ti won lo fun idanileko olojo-pipe (training) ni won fee bere sii mo bi
won se n lo ibon naa. Ana ojo Aje Monde ni idanwo naa ti bere ni aago mefa
aaro, ti yoo si pari loni ojo Isegun Tusde laago mefa irole.
Bakanna
ni won lo anfaani na lati gbawon araalu lamoran pe ki won ma se foya nigba ti
won ba n gbo iro ibon ni mesan-mewa, nitori pe ko sewu, atipe oke ni won maa
doju ibon won ko lasiko ti idanwo naa ba n lo lowo.
Nigba
to n soro naa fawon oniroyin lose to koja, agbenuso awon olopaa, Abimbola
Oyeyemi so pe adugbo Alamala loju ona to lo silu Ayetoro ni idanwo naa yoo ti
waye lojo kejilelogun si ojo ketalelogbon osu yi.
No comments:
Post a Comment