Mo saaju Pasuma bere ise orin – Alaaja Kubura - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 30, 2017

Mo saaju Pasuma bere ise orin – Alaaja Kubura

Bi e ba wa nibi ti obinrin yi ti n korin, se le maa ro pe Oloogbe Batili Alake lo n korin ni, bo tile je pe ohun tawon kan n so tele ni wipe leyin iku gbajumo Olorin Waka naa, ko seni to tun le dabi e mo nitori ti won ko le so boya a ri eni to ko nise orin tabi ko je pe ninu awon omo e gbegba orin, sugbon oro ko ri bee, nigba ti AWIKONKO ba Alaaja Kuburat Oritoke, eni to filu Ago Iwoye sebugbe pade nilu Abeokuta laipe yi, to si so awon ipenija ati adojuko e, eyi ti ko tii fun ni anfaani lati se rekoodu ti e jade, bo tile je pe orisirisi ode ariya lo ti n korin.

Alaaja Kubura Oritoke
Alaaja Oritoke nigba to n soro so pe ilumooka olorin Fuji nni, Alaaji Wasiu Alabi Pasuma ba oun lenu ise orin ni nitori pe odun 1984 loun ti bere sii korin ko too dipe Pasuma ronu lati bere sii korin, ki aye too mo.

O ni Pasuma maa n wa sibi toun ba ti korin, ko too gbegba orin ti e naa, to si maa n ki oun loju agbo bo tile je pe okunrin naa ko le ranti oun mo nitori pea won eeyan ti po, sugbon oun mo pe tawon ba si jo soro, o see se ko ranti oun.

Omo bibi ilu Ago Iwoye yi so pe leyin toun pari eko ni pamari siisi ni baba oun so pe koun ma da ara oun laamu lati lo sile iwe mo nitori awon eeyan ti so pe ise orin lounmaa se toun ba dagba. “Won wa mu mi lo si odo Oloogbe Batili Alake ni Ijebu Igbo lati lo ko ise orin, ti mo si lo odun mejo nibe. Odun 1977 ni mo de odo Batili Alake, 1983 ni mo se firidoomu, ti mo gbominira.”

O ni idi niyi toun ko fi ronu lati lo ko ise min in nitori ayanmo orin toun gbe wa saye. O tesiwaju pe odun kan, iyen odun Sofari tawon maa n se labule nigba naa, toun si maa n ko awon omode jo lati korin kaakiri aba, tawon eeyan si maa n fun won lowo lawon eeyan ti lo so fun baba ouun pe ibi toun ti le lokiki niyen, ki won lo fimi sodo eni ti yoo tubo ko mi nise orin.

Alaaja Oritoke tun so fun AWIKONKO pe awon ipenija ati adojuko toun ti ba pade ni ko je koun tii se awo rekoodu jade lati odun 1984 to ti gbominira lodo oga e, Batili Alake to ko o nise naa.

O ni awon oko toun n fe lo n se sababi ifaseyin ati ijakule toun ba pade lodo awon to ye ko ran oun lowo lati gbe orin jade, koun naa si di gbajumo laarin awon olorin Fuji, paapaa ni ti orin Waka toun yan laayo nitori pe won ko fe koun korin.

“Awon oko ti mo n fe nigba yen, opo won ni won je idena lodo awon to ye ko ran mi lowo, sugbon igba ti mo wa da duro, ti mo sunmo egbe FUMAN, ti mo n sunmo awon agbaagba bi alaga, ti won si n mu mi jade, lo ti n fi okan mi bale pe laipe, maa se rekoodu jade. Mi o tii so ireti nu wipe mi o le se rekoodu jade, niwon igba ti mi o bai ti ku, mo nigbagbo pe oluranlowo n bo.”

O wa rawo ebe sawon eeyan pe ki won siju aanu wo oun lati ma je ki talenti oun ku. O ni oun na ko duro, nitori pe awon to ye koun sunmo loun n sa gbogbo agbara oun lati rii pe oun naa se rekoodu toun jade nitori pe orin wa nile repete lati fi se rekoodu.

Bakanna lo so pe “Ko tii si olorin waka miran to si dide latigba ti Batili Alake ti ku, atipe emi ni Olorun fee lo lati gbe orin Waka dide pada, ti m ba ri eni to le ran mi lowo.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI