Nitori egberun meta, Amadi lu Omo e pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 21, 2017

Nitori egberun meta, Amadi lu Omo e pa

Ki Olorun ma je ki aye gba omo wa na, nitori eni ti aye ba gba omo e na, ana pa ni. Eyi lo ni ibamu pelu okunrin kan ti won pe oruko e ni Amadi, eni to ki omo e, omodun meje mole to si luu pa patapata.

Amadi ati oku omo e
Adugbo kan ti won pe ni Amadi-Ama, Port-Harcourt nipinle Rivers nisele naa ti waye ni nnkan bi aago mejila aabo oru ojo Abameta Satide to koja yi.

AWIKONKO gbo pe omo naa ko lati jise ti baba e ran lojo Eti Fraide, to si tun ji egberun meta gbe, eyi lo fa a ti won ni Amadi fi reke e, to si n wo titi to fi sun.

Sugbon nigba to di nnkan bi aago mejila geerege ni won ni Amadi lu omo e lati oju oorun, tomo naa si pariwo sita, ko too dipe awon araale dide lati lo be Amadi pe ko fi sile.

Sugbon ibinu ti won lo wa lara Amadi ko je ko gbo tawon to n bee pe ko roar na omo e, bo tile je pe won ko so oruko omo naa fun AWIKONKO. Nigba ti iya dun omo yi lo ba daku, ere ni won koko pe e tori won ni Amadi si n fese gba nile to wa.

Nigba ti won rii pe omo naa ko mira mo, lo je ki won sare gbe omi lati roo le lori, sugbon gbogbo igbiyanju ti won ni won gba lati ra emi omo yi pada lojo naa lo ja si pabo, aso ko bomoye mo, omoye ti rinhoho woja.

Pakopako ni Amadi n wo nigba to rii pe omo naa ti ku, to si kawo lori pe asise nla ti wole to oun. Loju ese ni won ti sare te awon olopaa laago lati foro naa to won leti.

AWIKONKO gbo pe iya omo naa ko gbe pelu baba e latari wahala ti won ni Amadi n fun nigba to wa lodo e, won ni se ni Amadi ati iyawo e to sese fe maa n fi ebi pa, ti won ko si toju e bii omo won.

Omo to lu pa
Okan lara awon araadugbo naa so pe oun si ri omo naa lojo Isegun Tusde to koja yi, nibi ti won ni o ti ji akara oyinbo (doughnut), tawon to jii lodo e si fun un si, ti won tun fun ni ounje.

Okunrin naa so pe oun tun muu lo sile lati lo se itoju e daadaa, toun si n ronu ona lati ran an lowo, ati lati gba kuro lowo awon to n fiya je. O so pe iyalenu lo je nigba toun maa ji laaro ojo naa, to je pe iroyin iku omo naa loun gbo, ti won so pe baba e ti lu pa.

Nigba to n jeri soro naa, agbenuso olopaa nipinle Rivers, Ogbeni Nnamdi Omoni so pe looto ni atipe Amadi ti wa lakolo won nibi tawon ti n foro wa lenu wo.

Omoni so pe leyin tawon ba pari iwadi won, ko si ona eburu ti Amadi yoo gba lati ma foju e bale ejo ko si jiya ese e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI