Kasnaty ti ta moto e o, okada lo n gun kaakiri igboro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 18, 2017

Kasnaty ti ta moto e o, okada lo n gun kaakiri igboro

O ma se o, opo lo fee mo idi ti ilumooka sorosoro ori redio ati telifisan, Ogbeni Kolawole Adejojo topo mo si Kasnaty fit a moto, to si je pe okada lo n gun kaakiri igboro. Oju ti yin, nitori pe odun 2013 lokunrin naa ta moto Camry onilekun meji e, to si ra oko Honda bogini to tun ju eyi to n lo tele lo.

Bo tile je pe iyalenu lo je fawon ololufe Kasnaty nigba ti won n ri kaakiri ori okada lodun naa lohun, tawon elenu marimaso si n so pe nise lo ta moto e fi jeun, lai mo pe o nibi to fee gba yo. Se won ni ile oba to jo, ewa lo bu si.

Bawon kan se n so pe boya nitori ooteli kan to sese gba to n mojuto ti won pe ni DE-SUITE to wa ni egbe ile Gomina Ibikunle Amosun,Ibara Housing niluu Abeokuta, bee lawon kan n so nnkan min in.

Bo tile je pe okunrin naa ko lo to osu meji to fi ti ooteli naa pa nitori gbese ti won so pe eni to n lo ibe tele ti je sile, eyi to koja agbara sorosoro naa, sibe awon to sunmo so pe owo kekere ko lo naa sibe, ko tun to tii pa.

Bee lawon kan so pe ko ma je pe owo moto e to ta yii lo fi ran ara e loo si ileewe awon to n kose ise iranse iyen pasito to sese pari. Ohun tawon kan ti e so nigba naa ni pe, ka ni o le gun rin irinajo loo si ilu odi keji ni, o ba lara mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI