Ogbologbo adigunjale meta lowo te l’Ogere - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 18, 2017

Ogbologbo adigunjale meta lowo te l’Ogere

Yinni-yinni keni o semi loro awon olopaa ipinle Ogun ri, nitori pe ko si ose kan kowo won ma tea won adigunjale nipinle, ise takuntakun ti won si n se losan loru lo n fa ti won fi n ri eran pa, nitori pe ode awon odaran ni won.

Ishola, Adetayo ati Adebayo
Lojo Aje Monde to koja yi lowo won tun bawon ogbologbo meta ninu ise adigunjale to je pe bi won ti n fo ile, bee ni won n dawon awako lona lawon opopona kaakiri ipinle Ogun, eyi to si ti ko iberubojo bawon araalu, paapaa awon to n wako ale.

Se Yoruba bo, won ni ojo gbogbo ni ti ole, ojo kan soso si ni ti olohun, eyi to si lo ni ibamu pelu bi owo se ba Abdul Azeez Ishola, Adetayo Gbenga ati Adebayo Samson lagbegbe Ogere ni nnkan bi aago mefa koja ogun iseju, lakoko ti won tun n gbiyanju lati dawon awako lona gba owo ati dukia lowo won.

AWIKONKO gbo pe opopona Eko si Ibadan lawon ogbologbo odaran yi ti maa n sise ju, oru dudu si ni won maa n sise won ju, ti won si maa n fagidi gba nnkan lowo awon onimoto.

Awon araalu to n koja lo, to ku die ko ko sakolo won lo sare tete lo tu asiiri sita fawon olopaa to n so togeeti Ogere, ko too di pe Ogbeni Paul Omiwole pelu awon olopaa toku lo koju awon odaran naa ti won si ri won nibi ti won sapamo si, ti won n wa eni ti yoo ko sakolo won.

Aye mi baje” lorin ekun ti won mu bo enu nigba tawon olopaa ko won, ti won si ko won de tesan. Agbenuso olopaa, Abimbola Oyeyemi nigba to soro naa fun AWIKONKO, O so pe Ibon ilewo meji, ota ibon meje, aago owo meji, ero ibanisoro mokanlelogun ati egberun merindinlogun ataabo ni won gba lowo won loju ese ti won mu won ti won si tun ka gbogbo ese ti won ti n se bo.

Komisana Olopaa, Ahmed Iliyasu ti wa pase pe ki awon olopaa digboluja FSARS lo tubo foro wa won lenuwo. O si fokan awon araalu paapaa awon to n rin lona naa bale pe ko sewu fun won mo nitori pea won yoo tun ko awon olopaa repete sopopona kaakiri lati daabo bo emi ati dukia awon araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI