Okurin tiyawo e bi ibeji leemarun so pe awon obinrin ko je koun gbadun ladugbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 9, 2017

Okurin tiyawo e bi ibeji leemarun so pe awon obinrin ko je koun gbadun ladugbo

Ko seni to gbo nipa obinrin to bi ibeji leemaarun otooto ti ko ni lanu se “ha” titi ti ito yoo fi maa jabo lenu e, nitori bi aditu loro oun ati oko si n je fawon araalu paapaa awon omo Naijiria tiroyin naa te lowo.

Ayo, Bose atawon ibeji won
Gege bi AWIKONKO se gbo, arakunrin kan, Ayo Ogunneye tawon eeyan mo si Baba Ibeji ti won ni ise kafinta lo n se ni iyawo e, Bose Ogunneye bi ibeji akoko lodun 2008 to si je pe ko pe tawon omo naa fi jade laye.

Lodun 2009 ni Bose tun loyun miran, sugbon nigba to maa bi omo naa, obinrin meji lawon omo to bi, eyi lo je ko se awon eeyan ni kayeefi pe awon omo to ku lakoko lo tun pada wa leekeji. Iyalenu lo tun je lodun 2011 ti Bose, tojo ori e ko tii ju odun meedogbon fi oyun to ni bi ibeji, okunrin kan ati obinrin kan.

Ko tan sibe, lodun 2013 ni Bose tun bi awon ibeji miran, to fi je eleekerin, latigba naa la gbo pe awon obinrin adugbo paapaa nijoba ibile Ado-Odo Ota ti bere sii da oko e, Ayo laamu pe ko wa a fi ibeji ta awon naa lore, ti ko si gba fun won.

Bi e ba de ilu Ado-Odo ti e so pe Baba Ibeji le n beere, bo tile je pe kii se Ayo nikan ni okunrin tiyawo e bi ibeji nibe, sugbon ile e to n gbe ni agboole Idobalure lawon eeyan yoo juwe fun un yin, tabi ki won muu yin debe.

Lodun 2014 tawon araalu tun ri oyun ninu Bose ni won ti bere sii ki ku oriire pe ibeji ni yoo tun fomo naa bi, bo tile je pe awon kan so pe ko tun le bi ibeji mo. Ohun ti a gbo nipe awon kan ti e foro naa ta tete pe ibeji kon ni yoo foyun naa bi, sugbon siyalenu nigba ti Bose yoo fi oyun naa bimo lojo kerinla osu keje odun 2015, okunrin kan ati obinrin kan lo bi, sugbon o seni laanu pe eyi obinrin naa gbemi mi leyin bii wakati melo kan.

Eyi ni won loo fa to fi je pe okunrin naa kii fee jade nile mo nitori ti won so pe gbogbo ibi to ba gba lawon obinrin ti n dena de pe dandan afi ko bawon lasepo ko si fun won loyun nitori pe o wu awon naa lati bi ibeji.

Ayo atiyawo e Bose nigba ti won n ba AWIKONKO soro lori bi oro ibeji naa se je, ati awon ipenija ti won n koju, Bose Ogunneye so pe bo tile je pe oun dupe lowo Olorun fun oore ofe to fun oun lati da awon ibeji naa bi layo ati alaafia, sugbon edun okan lo tun je foun lapa kan wipe awon obinrin ko fee je koun gbadun oko oun nitori pe won n gbiyanju lati gba oko mo oun lowo nitori ato ibeji to wa lara e.

O loun ko tun le gbadura fun okunrin miran bi ko se oko oun ayo nitori pe bo tile je pe ko lowo lowo, sugbon omo ere se lori beedi, ko si sigba toun so pe o ya ti ko ni da oun loun. O rawo ebe si Alaga ijoba ibile Ado-Odo, iyen Saheed Alagbe lati ba oun wa ise ti yoo maa fi ri owo lati ran awon omo won lo sile iwe.

Ayo nigba toun naa soro tenu mo pe aditu loro naa si n je foun wipe ato ibeji loun gbe was aye eyi to si seese koun gba aami eye, iyen awoodu gege bi okunrin to ni ato ibeji nitori pe iru e ko tii sele ri lorileede Naijiria.

O so pe, oun si wa lori ipinu lati maa bu owo fawon obinrin to ba fe koun bawon lasepo, bii egberun lona aadota lori ibasun eekan pere lati le maa fi ri owo toju awon omo oun, koun si ri owo fi ran won lo sile iwe.

Awon mejeeji wa rawo ebe sijoba ipinle Ogun atijoba apapo lati ran won lowo lati toju awon omo naa, nitori pee to oro aje to dori kodo ko je kowo maa wole bo se ye ko wole fawon gege bi ise kafinta ti Ayo n se. Bakanna ni won dupe lowo awon araalu fun iranlowo ti won n ri gba lati odo won lori awon ibeji won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI