Owo olopa te Mathew atiyawo e to n lu jibiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 9, 2017

Owo olopa te Mathew atiyawo e to n lu jibiti


Kayeefi loro oko atiyawo Mathew Abioro ati Precious Oyekunle Abioro tasiri won tu sawon olopaa lowo lojoru Wesde ose to koja lagbegbe Sango lakoko ti won tun fee lo pawon eeyan lekun gege bi won ni won se n ma n se.

Matthew ati Iyawo e
Gege bi AWIKONKO se gbo, Abeokuta ni won ni Mathew atiyawo e, Precious n gbe, to si je pe Sango si Abeokuta naa ni won ti maa n jale won. Sugbon lojo towo palaba won segi, lara awon araadungbo Sango ti won ti lu ni jibiti ri lo ta awon olopaa lolobo pe won ti wa nitosi lati tun wa se bi won se n se e.

Gbara ti won lawon FSARS ti gbo ni won ti gbera lati loo koju won ti won si ri won nibi ti won maa n sapamo si ki won too sise, ati leyin ti won ba sise won tan.

“E se wa jeje” ni won loro ebe to n jade lenu won ko too dip e won ko won de olu ile ise olopaa to wa ni Eleweran lati tub o gboro lenu won lori bi won se n sise ibi won.

Mathew ati Precious nigba tawon olopaa n foro wa won lenu wo so pe looto lawon ti n jale tawon si ti n lu jibiti tipe, sugbon oro atije lo sun awon debi iwa adojutini naa. Won ni Kutonu,  Orileede Benin  lawon maa n ta eru tawon ba ji si, ki asiri ma baa tu.

Siwaju sii ni Precious so pe okada tawon ole gba ja gba, ti won bag be fun awon, orileede Benin lawon maa ta si tawon si ma fi n ra irinse bii ibon tawon maa n lo lati fi sise.

Agbenuso olopaa, Abimbola Oyeyemi nigba to n soro naa fakoroyin wa nirole ojo Abameta Satide so pe Orisirisi ibon at iota lawon ri gba lowo won, sugbon Oga awon, Ahmed Iliyasu ti so pe ki won tubo tea won eeyan naa ninu daadaa, ki won sir ii pe won jewo awon ti won jo n sise.

Iliyasu so pe bo tile je pea won mejeeji naa ko ni pe e foju bale ejo, sibe oun ko ni fi aaye gba awon to odaran to ba n gbero lati da alaafia awon araalu laamu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI