Won niku Moji Olaiya kii soju lasan, o lowo aye ninu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 21, 2017

Won niku Moji Olaiya kii soju lasan, o lowo aye ninu

Bo se je pe opo awon eeyan lo n so orisirisi oro nipa iku to pa gbajumo oserebinrin Moji Olaiya to ku l’Ojobo Tosde to koja yi ni nnkan bi aago meta oru ni Osibitu Humber River to wa ladugbo Keele ni Wilson Avenue, Toronto nilu Canada.

Moji Olaiya
Gege bi e ti mo pe IROYIN AWIKONKO kii se iwe iroyin ori ero ayelujara to n gbe ayederu iroyin jade, nitori pe awa kii figba kan bo okan ninu, a so loju oloro ni IROYIN AWIKONKO je laarin awon iwe iroyin toku, kii se awa, Olorun Oba ni.

Ohun ti a gbo nipa iku Moji Olaiya ni pe kii soju lasan, o lowo aye ninu nitori pe ko si nkan to se e ko too ku iku ojiji lojo naa. Won ni o si bawon eeyan soro ni nnkan bi wakati meji ki olojo too de.

Bi e ba tun n wa eni to sunmo Moji Olaiya julo, yato si Bisi Ibidapo Obe, iyen Omologbalogba, Arabinrin kan ti won pe oruko e ni Keji lo tun sunmo ju bi isan-orun nitori oun lo maa n ran Moji lowo ninu ile, paapaa to n setoju mama e ti ko ba ti si nile.

Moji ko too ku la gbo pe kii foro pamo fun Arabinrin Keji, won si mo irin ajo ara won.

Nigba to n soro lori iku to pa Moji, Arabinrin Keji so pe iku naa lowo aye ninu nitori igbagbo oun ni pe kii soju lasan. O lawon eeyan le maa so nnkan to ba wu won, sugbon nnkan to da oun loju nipe ise aye ni.

O ni oun loun tun sunmo Moji ju atipe o ku ojo meta ko ku lo ti n pe oun wipe oun ko mo bi ara se n se oun, toun si gba lawon amoran kan.

“Kogbokogbo lomo ti Moji bi nitori pe akosile oyun e so pe inu osu karun yi lo ye ko bimo naa, to si je pe osu meji seyin lo ti bi. Nnkan to faa ni pe ipo ti won lomo naa wa ko dara, ti ko ba si tete bi, o seese ko ku sinu, nnkan to je ki won tete fi ise abe gbe omo naa jade niyen.

“Aisan yi dide leyin to bimo naa tan, toripe ojoojumo lo maa n so pe oun ko gbadun ara oun. Ni nnkan bi aago mewa ale (gege bi onka ilu Canada), iyen laago meta oru tiwa nibi, eje Moji bere sii ru to si daku. Awon ti won jo wa ni won sare pe oko pajawiri nile iwosan to sunmo won lati waa gbe. Inu moto naa lo dake si ki won too dele iwosan” Arabinrin Keji soro.

Wakati mejidinlogun ki Moji too ku lojo Tosde, nnkan to ko gbeyin sori ero ayelujara Instagram ni pe “Eyin ore mi, Okiki app ti wa larowoto nibi ti e ti le ni lori foonu yin. E maa jegbadun awon sinima lati owo mi ati lati owo awon agba osere to ku lofe.” (“Hello fans, Okiki app is now on Apple App Store. Watch movies from me and other great actors for free.”)

Sugbon ko too ko eyi lo ti koko gbe aworan foto ara e, to si ko nnkan mi in to fi dupe lowo Allah lojo Tusde pe “Alliamdulilahi fun iwo Allah, mo fi gbogbo ope fun O fun awon nnkan too ti se. Kii se agbara mi bikose oore ofe Allah. Ese fun ebun aaye. Ope mi lowo eyin ore mi, ebi mi ateyin ololufe mi fun igbarukuti ati adura yin. Mo nife yin pupo.” (“Alliamdulilahi to you Allah I give all the glory for all you have done. I will forever praise and worship you. It’s not by power but the Grace of Allah. Thank you for the gift of life. Thanks also to all my friends and family my fans for your supports and prayers. Love you all.”)

Adunoluwa Ajokeade Farombi, omo Moji
Adunoluwa Ajokeade Farombi, omo Moji Olaiya nigba to n soro pelu ibanuje okan so pe ko tun si iru iroyin to tun le ba oun lokan je ju iku iya oun lo, nitoripe awon si soro ni nnkan bi wakati merin ko too ku, toun ko si gbo firifiri wipe o le ku kile too mo.

Adunoluwa so pe oun ko mura sile nipa iku iya oun, ibanuje ati edun okan nla lo je foun. O so pe oun ko le gbagbe mama oun toun naa maa fi ku nitori bo se maa n toju oun. O ni ko si nnkan toun fe ti mama oun kii se foun lasiko toun ba ti fe e si.

Nigba to n soro bi isinku mama e se maa lo si, Adunoluwa so pe oun ko le so, awon ebi lo lase lati so bi eto isinku yoo se lo si. O ni nnkan toun kan fe nipe won o gbodo sin mama oun silu Canada.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI