Won tun ti kede aisan iba LASSA ni Port Harcourt - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 16, 2017

Won tun ti kede aisan iba LASSA ni Port Harcourt

Lojoru Wesde ana nijoba ipinle Rivers so pe looto ni aisan iba LASSA miran tun ti jeyo nipinle naa, eyi ti won so pe ise ti n lo lowo lati ma je ki aarin naa yika ipinle naa, lori bo se je pe ileewosan aladani kan ni won ti sawari e.

Komisana foro ilera nipinle naa, Ogbeni Theophilus Odagme nigba jeri soro naa so pe kawon eeyan ma se foye lori aisan iba aseku pani naa nitori igbese ti n lo lati da itankale aisan naa duro.

O so pe ara alaisan kan ti won gbe wa sileewosan aladani kan ni won ti sawari aisan iba naa, sugbon tawon akosemose dokita si ti n wa ona abayo sii, iyen ni pe lati tele ilana ti ajo onilera agbaye, World Health Organization, WHO la kale lati fi wo aisan naa, ti ko fi ni tan kaakiri.

Komisana naa so pe awon ti n bawon ajo WHO soro lati rii daju awon molebi eni ti won sawari aisan naa lara e ni won gbodo gba itoju to peye lati ma se je ki won tan aisan iba naa kaakiri.

Odagme wa ro awon araalu pe ki won maa je kawon to mo nipa oro ilera mo nigba ti won ba sawari pe eni kan n po eje tabi won ri eje.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI