Awon agbaagba lo n da egbe FIBAN ru l’Ogun – Angel - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 10, 2017

Awon agbaagba lo n da egbe FIBAN ru l’Ogun – Angel

Odu ni gbajumo sorosoro nni, Jeleel Ajayi topo mo si Angel nidi ka gbohun safefe kii saimo foloko paapaa nileese redio aladani Family FM to wa nilu Abeokuta, okunrin naa so lori isoro to n koju egbe naa latari awuyewuye ati ikunsinu to n lo laarin awon omo egbe naa fun ti idibo to m bo ninu osu keje odun yi.

Angel Ajayi
Ojoru Wesde to koja yi ni Angel Ajayi so nipa ibi ti ipile naa ti wo wa lakoko to ba AWIKONKO soro nilu Abeokuta.

Ko tii seni to le so ibi toro naa maa fori sole si titi di bi a ti n koroyin yi latari wahala ati awuyewuye to n sele ninu egbe sorosoro, Freelance and Independent Broadcasters’ Association of Nigeria, FIBAN eka tipinle Ogun.

Ko soun meji to n da wahala ati awuyewuye sile laarin awon omo egbe naa bi ko se ti idibo sipo alaga to fee waye ninu osu keje to m bo yii, to si ti da ote sile laarin won, to tun je ki egbe naa pin sona meta bayii.

Okan lara awon omo egbe naa, eni to so pe oun ni won fee lo fun alaga tele sugbon toun so pe asiko ko tii to, kawon agbaagba si maa tesiwaju lo naa, digba ti asiko toun yoo fi de, Jeleel Ajayi topo mo si Angel leni naa.

Okunrin naa ti soko oro sawon agbaagba pe awon gan an ni igi leyin ogba to n da egbe FIBAN ru, latari bi enu won ko se ko lati bawon omo keekeeke egbe naa soro, o ni won ko lenu oro lati pase fawon omoleyin won nitori ote.

O ni nigba toun fee darapo mo egbe naa, bo tile je pe oun ti n seto lori redio nipinle Ekoo koun too wa tedo silu Abeokuta, akiyesi toun se ni pe agbekale ote lawon agbaagba egbe naa fi n ba ara won se po, eyi tawon omo leyin won si n wo awokose e fi siwawu.

Angel so pe nigba ti won ti oselu bo oro idibo ni won bere sii fi ote le awon kan kuro, ti won barawon ja gidi. O ni awon eeyan bii Asamu Akinrinde, Abiodun Muibi, Desmond Nwachukwu ti se alaga, sugbon o je pe latigba naa ni ote ti bere, ti won ko lo ife lati ba ara won se, nitori pe odo awon agbalagba lo ye ki ife ti bere kawon to m bo leyin si maa wo awokose won.

O lawon agba ko fi ipile rere lele fawon odo to n bo leyin, to je pe seni won a maa binu ara won, ti won a maa soro ara won leyin, ti won a maa ba ara won loruko je. O so pe nigba ti Desmond se, ariwo pe o kowo je ni won n pa kiri, to si je pe okunrin naa ko ri owo ileewe omo e ati ile to n gbe san nigba naa.

Angel lopo awon agbalagba egbe naa ni ko san owo (dues) ti won maa n san losoosu, o ni nigba tawon agbaagba ko san owo yi, to je pe won a tun pe de ipade, bawo lawon to n bo leyin se fe e san ti won, awokose ni won a maa wo. O tesiwaju pe orin pe eni kan ko se daadaa ni won n pa, ki ni nnkan ti won n wo nigba naa ti won ko le ba eni naa soro.

Okunrin naa tun so pe ko ye ki nkan ti won n pe ni faction wa ninu egbe sorosoro rara, nitori pe se lawon araalu n wo awon gege bi awokose, gege bi ebi to mo nkan tan, ti awon eto won si n tun opolopo idile se. o loo seni laanu pe awon tawon so pe awon n tun idile onidile se ni idile ti won gan an o da, toripe FIBAN, idile kan ni.

Ninu oro e, “Ote ti won n se yi ti poju, won n binu ara won ju, nigba ti eni kan ba joye, ti e maa ko awon eeyan jo lati dite yo o kuro, ko ye ko ri bee.”

Bee lo tun so pe nnkan to n da wahala sile ju ni ti aini eto, ilana, agbekale ati ofin to de eto idibi, “Ni bayii, ti a ba n so nipa awon agbaagba FIBAN, e wo iru idibo to n bo yi, to ba je pe agbekale kan ti wa tabi atunse agbeyewo agbekale, bii ki won so pe iwo ti o ba fee jade, o ye ki o ti lo iye odun bayii ninu egbe, tabi ojo ori e gbodo je odun bayii ki o too dibo.

“Ko si ofin to de idibo rara, awon omode o le pase idibo, awon agbaagba ni won lase lati pase idibo, sugbon awon agbaagba kan wa to je pe bi eni ti won o fe ba ti wole, won a bu ile ipade dani, won ko nii wa sipade mo, o tun die yin odun metta tabi merinti won bat un ni nnkan se ko tun to yoju, ko ye ko ri bee.”

 O so siwaju pe nitori a ti ri owo gba lowo awon eeyan lo se n dupo ninu egbe, to si je pe se lo ye ki won gbe egbe naa gun oke agba, o ye kawon ti won pe ara won ni agbalagba jokoo papo lati so asoyepo, ki won se atunse, sugbon owo ti won n wa ko ni je ki won ronu lo sibe.

O so pe egbe to ti gbooro ni FIBAN je, sugbon ijoba ko mo won bo se ye, won ko fun won ni owo (respect) to ye ki won fun won nitori opo awon agbaagba yi gan an ni won maa n bu ijoba, to si je pe ijoba tawon gan an se, ko se e gbo seti. O laini idanilekoo lore-koore fawon omo egbe, sugbon ti ko si nitori pe eru kan nii mu nib u igba eru.

O so pe bo tile je pe oun kere lati gbawon lamoran, sugbon oun tun gbodo soro pe kawon agbaagba FIBAN lo tun ijokoo jo tai se atunyewo ati atunse ofin, ti ko ba si ofin tele, ki won lo gbe ofin maa de gbogbo omo egbe kale, eyi ti yoo tun so nipa eto idibo ninu egbe. Bee lo ni kawon to n bo leyin naa maa wo awokose rere lara awon agbaagba ko ma je pe eyi to ku die kaato ni won a maa wo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI