Awon eleegun kolu Mosalasi l’Ekiti lakoko isinu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 1, 2017

Awon eleegun kolu Mosalasi l’Ekiti lakoko isinu

Iyalenu loro awon eleegun ti won kolu awon musulumi ninu mosalasi ti won ti n kirun lati sinu fun ti aawe ti won ti n gba lataaro lagbegbe nilu Ikun Ekiti, ijoba ibile Moba si n je fawon araalu.
 
Ibi isele na, ati Imaamu Bello
Gege bi AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago meje ale ojo Isegun Tusde lawon eeyan naa lo kolu nibi ti won ti n kirun, nigba ti won so pe se ni won n di awon lowo fun ti ayeye odun eegun won to n lo lowo.

Bi won se perun lati bere ikirun won ni won lawon eleegun naa de, ti won si duro senu ona lati lu awon musulumi naa bi won ba se n jade, sugbon se ni won so pe fun bii wakati merin lawon eeyan naa fi sa sinu mosalasi ti won ko jade sita.

Nigba tawon eleegun naa rii pe won ko fee jade, asiko si n lo, lo mu ki won ja ilekun mosalasi wole loo ba won, ti won si lu won bi eni lu ilu bata, opo awon eeyan to wa ninu mosalasi lojo naa la gbo pe won gba apa lara won.

Imaamu Bello
Bee ni won fo aafa kan lori, paapaa awon moto meji ti won paaki sita mosalasi naa fara gbota nigba ti won lu moto naa fo yanna-yanna.

Adele Imaamu mosalasi naa, Alaaji Abdul-Rasak Abubakar-Bello toun naa wa ninu mosalasi lasiko naa la gbo pe won sare gbe lo si osibitu EKSUTH, iyen Ekiti State University Teaching Hospital to wa ni Ado Ekiti nibi ti won ti ran ori e tawon janduku naa fogi mo.

Nigba to n ba AWIKONKO soro lori beedi ile iwosan nibi to ti n gba itoju so pe fun bii wakati merin ni won fi duro lenu ona lati wole wa ba won, sugbon nigba tawon ko tete jade sita lo mu ki won ja ilekun waa bawon.

O so pe gbogbo bawon se ranse pe awon olopaa lati waa gba awon lo je pe se ni won koti ikun sawon, ti won ko dawon lohun. O so pe ko si olopaa to yoju titi tio won fi se awon lese.

Bee lawon agbarijo musulumi lagbegbe naa bu enu ate lu iwa ti kabiyesi won hu, iyen Oba Olatunde Olusola fun bo se sagbateru iwa tawon eeyan naa hu lasiko tawon n ke pe Olorun won.

Lara awon to farapa
Nigba toun naa n soro gege bi esun ti won fi kan an, Oba Onikun, Oba Olatunde Olusola so pe lojo kerindinlogbon osu to koja lawon ti ko leta sawon musulumi kaakiri ilu naa pe ki won fun awon ni aaye ojo yen lati fi se odun eegun tawon fee se.

Won ni lati yago fun wahala lawon se rawo ebe si won, sugbon iyalenu lo je nigba tawon tun ri won pe won ko tewo gba leta awon, ti won si se nkan tawon ni ki won ma se.
O lopo igba ni wahala ti maa n sele laarin awon atawon musulumi nilu naa nitori pe ojubo tawon ti n se etutu ko jina si mosalasi naa, nitori e lawon se maa n rawo ebe siwon pe ki won fun awon laaye lati se nkan tawon fee se.

Kabiyesi so pe kii se awon musulumi nikan lawon n ko leta si lati rawo ebe si, bi ko se gbogbo awon toro ba kan nilu naa pe ki won fun awon laaye ojo tawon fee fi se odun won.

O ni iyalenu lo je nigba tawon eeyan bere sii se odun eegun naa, ti won si n gbaradi lati bere ni pereu lawon musulumi naa bere irun kiki won ni nnkan bi aago meje ku ogun iseju, eyi lo si se awon eeyan ni kayeefi pe ki lo n sele.

Bee lo so pe kani awon eeyan n se adura won ni kelekele ni, sugbon won o gbo nitori pe oun ran awon oloye lati loo ba won soro. O ni kani oun ko tete da si oro naa ni, ko ba le ju bi won se lero lo.

Agbenuso awon olopaa nipinle naa, Ogbeni Alberto Adeyemi nigba toun naa n soro, o so pe looto lawon gbo si isele naa sugbon awon ti yanju fun won ni tubiinubi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI