Ganzallo |
Ganzallo soro yi lojo
Aje Monde lakoko to n b’AWIKONKO soro ni ofiisi e to wa ni Oke Ilewo, Abeokuta
nibi to ti so awon aseyori e laarin odun kan to wa gege bi Komanda ajo naa
nipinle Ogun.
O so pe laarin odun
toun de ipo naa, opolopo nnkan loun ti yi pada bii iwuwasi awon osise won pelu
ofin to de won, nitori pe nnkan to wu won ni won n se tele, o lawon ti fofin de
gbogbo lori bi won se gbodo se.
O ni oore-koore
lawon n se idanilekoo fawon osise won nipa imura won, tori pe opo won ni kii fo
aso won tele, to je pe eekan lose tabi ose meji ni elomin in maa n foso e,
sugbon iyen ko ri bee mo bayii.
Gazallo lawon ti gba
awon eeyan repete sidi ise naa, ti won si n gbowo osu won bo ti to ati bo se
ye, sugbon kii se awon ti ko loye, o ni kawon ti won n fidi remi leyin iwe mewaa
won ma ro pe awon le bawon sise nitori pe awon ko nii gba won, o niwe eri iwe
mewaa won gbodo yanranti.
Bee lo lawon ti da
ileewe Fijilante sile, ti a pe ni Vijilante
Academy to wa nilu Ilaro nibi ti won ti n ko awon eeyan leko. Ijoba ipinle
Ogun lo si fun won nibi ti won n lo, ti won si fun won lawon nnkan to ye ki won
ni, eyi to n mu ise rorun fun won.
Nigba to n soro lori
awon ipenija, o ni aini to owo nisoro tawon n koju nitori pe opo nkan lo ye kawon
se, sugbon tawon ko lese nitori owo ti ko si. Ninu oro e, “Ipenija ti a ni ni
ti aini owo to to, eyi to n ba gbogbo awon ijoba wa finra. Awon nkan to ye ka
ri gba lati owo ijoba lati fi se awon nnkan ti a fee se.
“Aini owo ni ko je
ki a le e awon nnkan min in. Ti e ba wo gbogbo awon oko wa ti a n lo, ti a n pe
ni patrol vehicle yi lawon oko ti a ti gba lati odun 2011, to je pe won ti gbo,
won ti denu kole. Ara ipenija ti a ni niyen, sugbon a tiraka lati tun won se,
won ti pada senu ise, eyi naa tun je lara awon aseyori ti mi o ranti menuba. Ipenija
nla to daju ni ti ainito owo.”
Fun awon to ba mo, ojo kejila
osu karun to koja yi ni Soji Ganzallo pe odun kan lori ipo gege bi State
Commander ajo VSO. Ogun State Agricultural Development Programme ti a mo si
OGADEP lo ti bere ise ijoba nibi to ti kuro lo ko eko nipa ise eto aabo nilu
Oyinbo, ko too pada wa pelu da ajo Fijilante sile lodun 2011 nibi to ti je
alukoro lodun naa.
No comments:
Post a Comment