Ko sija laarin emi ati Sabo City – Oyama Azeez - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 10, 2017

Ko sija laarin emi ati Sabo City – Oyama Azeez

Ilumooka olorin Fuji nni, Adebola Azeez Gafar topo mo si Oyama Azeez ti pariwo sita wi pe ko sija laarin oun ati okan lara awon gbajumo sorosoro, Saburi Oladeji tawon eeyan mo si Sabo City, eni to filu Abeokuta sebugbe.

Sabo City ati Oyama Azeez
Oyama Azeez to filu Ekoo sebugbe soro naa l’Ojobo Tosde ose to koja wipe aheso oro lasan ni nitori pe ko sigba toun ati sabo City kii soro lori aago, paapaa toun ba kuro lorileede yi lo sorileede miran bii Dubai, South Afrika lawon fi n soro.

O ni ko si nkan to n je Oyama Azeez lai si Sabo City nirori pe eeyan toun kii foro pamo fun ni, atipe ko si nkan tokunrin naa ko mo nipa oun. O so pe nigba toun de lati Dubai laipe yi, oun ati Sabo City jo wa lagbo Welcome Dance tawon ololufe oun sagbateru e nilu Ota, lati fi ki oun kaabo.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won so pe owo lo daja sile laarin sorosoro naa, iyen Sabo City ati Oyama Azeez tawon mejeeji ko fi jo wa papo mo bii ti tele, nitori ko sibi ti Oyama Azeez ti korin ti Sabo City ko nii si nibe.

Awon ti won maa n ri awon mejeeji papo je ko ye wa pe owo lo daja sile laarin won, atipe won ni Sabo City tun n wa ojurere Oyama pada lo je ko maa lo awon awo orin Oyama Azeez lori awon eto e to maa n se lori redio kaakiri ipinle Ogun.

Oro naa tun jeyo nigba ti Sabo City se ikomo omo e laipe yi ti won ni Oyama Azeez ko yoju, nitori pe ko si ayeye ti Sabo City se ti Oyama ko ni si nibe, sugbon eyi lo tun je kawon eeyan ro pe nnkan n lo labele laarin awon mejeeji.

Oyama so pe oun kii se eni ti owo jo loju, oun ko si le fi aaye sile ki owo toun ba nile aye daja sile laarin oun ati eeyan nitori pe afowoba fiile nile aye je, bee lo so pe Sabo City kii se olojukokoro owo, ati pe eni tawon ti jo wa tipe ni, to si mo opolopo nnkan nipa oun.

O tesiwaju pe ise ti Sabo City n se lo faa ti ko fi ri aaye lati maa was awon ibi toun bat ii lo sere, nitori pe opo igba toun ba lo sere lo maa n je pe ori afefe, iyen redio ni Sabo City maa wa lati seto.

Nigba toun naa n soro, Saburi Oladeji, Sabo City so pe asiko toun fi n seto tele ti yato si tigba kan toun maa n ri aaye lati loo farahan nibi ti Oyama ba ti lo o korin, o ni ojo Eti Fraide ati Abameta Satide lawon eto oun bo si niisinyi, to si je pe awon ojo naa ni Oyama maa n lo sere, eyi kii fi aaye sile foun lati loo ba.

O ni ko si nkan to le da aarin oun ati Oyama Azeez ru nitori pe ore timotimo lawon je, tawon si ti mora tipetipe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI