Nitori YAYI, Ogogo soko oro si Gomina Amosun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 3, 2017

Nitori YAYI, Ogogo soko oro si Gomina Amosun

Gbajumo osere tiata nni, Alaaji Taiwo Hassan topo mo si Ogogo Kulodo ti bu enu ate lu Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun lori oro to so pe awon Yewa n sagbateru adije Tekobo lati dije dupo gomina nipinle naa.
 
Ogogo Kulodo
Ogogo soro yi nibi eti idanileko ti Aawe Ramadan to waye ni gbagede Asade Agunloye to wa nilu Ilaro lakoko to n bawon akoroyin soro, o so pe bo ba je looto ni Amosun fee gbaruku ti Yewa lati depo gomina, ko ye ko maa so awon oro abuku naa jade lenu.

O lawon mo nkan tawon n se nitori pe awon da ara won mo, atipe Senato Solomon Adeola, iyen YAYI je eni tawon bu ola fun gidigidi nitori pe omo bibi Yewa ni, kii se Tekobo rara, ojulowo omo Yewa si ni.

Ogogo ni omo awon lati Ishaga Orile ni agboole Pahayi ni Yayi je, kii se Tekobo ti Gomina Amosun pe nita gbangba. O ni bo ba je looto ni Amosun fe ki Yewa gba Gomina lodun 2019, ko ye ko fi oju saaju soro naa.

Bi e o ba gbagbe, lojo Isegun Tusde to koja ni Gomina Amosun so pe boun ba ti e fee tele ipinu to wa nile pe Yewa lo kan ti won n pariwo, kii se Tekobo ti won lo o gbe wa loun maa bawon fowo si.

O ni bi adije kan ba jade lati Ogun Central, oun ko nii fowo si, oun yoo tako lakoko ipolongo. Bi enikeni ba jade l’Ogun East, o seese koun ma tako lakoko ipolongo idibo, sugbon oun ko nii fowo si. O ni adije to ba jade l’Ogun West iyen ni Yewa loun yoo tele, sugbon kii se adije Tekobo ti won n pariwo e.

Amosun ni kawon Yewa tubo loo jokoo lati forikori lori eni ti won ba fe lati gbajoba ipinle Ogun lodun 2019, ti kii se Tekobo. O ni yato si gbajumo Tekobo ti won mo, won tun n gbero lati ko awon Tekobo meji kan wa, tawon ko si nii gba. O wa ro won pe ki won lo tun ile won to daadaa ki asiko ipolongo too de.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI